Olumide pera ẹ loṣere tiata, ṣugbọn gbaju-ẹ gidi loun atọrẹ ẹ n ṣe n’Ibadan

Faith Adebọla

Ọkunrin kan, Olumide Ọlajide, to sọ pe ọkan lara awọn oṣere onitiata ilẹ wa loun, wa lara awọn afurasi ọdaran tileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ṣafihan wọn lọjọ Aje, Mọnde yii, ẹsun lilu awọn eeyan ni jibiti owo ninu akaunti banki wọn ni wọn fi kan an.

Awọn meji ni wọn fẹsun kan pe wọn jọ n ṣiṣẹ buruku ọhun, Wẹmimọ Adeyanju lorukọ ẹni keji, wọn ṣafihan oun naa, wọn nileewe poli kan loun ti n kawe, ipele giga HND lo si wa.

Gẹgẹ bawọn ọlọpaa ṣe ṣalaye, wọn ni niṣe lawọn ọdaran yii maa n lọ sọdọ awọn to jẹ oniṣowo, wọn aa ṣa awọn ọja ti wọn fẹẹ ra ninu igba wọn, wọn yoo si sọ fun wọn pe niṣe lawọn maa fowo ṣọwọ si wọn latori ẹrọ tabi foonu awọn, eyi tawọn eleebo n pe ni Bank transfer.

Wọn ni bi ọlọja naa ba ti gba, awọn afurasi yii maa ni ko fawọn ni nọmba akaunti rẹ ati orukọ banki tawọn maa fowo ṣọwọ si. Ti wọn ba ti tẹ koodu (code) to yẹ, wọn maa ri ohun gbogbo nipa ọlọja yẹn lori foonu wọn.

Olumide fẹnu ara ẹ sọ fawọn oniroyin pe gbara tawọn ba ti mọ nọmba akanti ati banki ati orukọ onitọhun, oju-ẹsẹ loun maa wa ọkan ninu awọn atẹjiṣẹ ti banki naa ti fi ranṣẹ sonibaara wọn ri, awọn maa yi awọn nnkan kan pada ninu atẹjiṣẹ naa ko le jọ bii pe banki yẹn lo ṣẹṣẹ fi i ranṣẹ, o si maa ba owo to ba transifaa mu, ki tọhun too fura, wọn ti palẹ ọja mọ, wọn ti bẹsẹ wọn sọrọ.

Lọjọ tọwọ palaba wọn segi, Wẹmimọ ni “obinrin kan tawọn ti ṣe kinni naa fun ri, ṣugbọn tawọn o ranti ẹ mọ lo ri awọn ninu ṣọọbu kan tawọn ti fẹẹ lu jibiti ọhun, lobinrin naa ba wo oju wa ninu fọto Wasaapu wa to wa lori foonu ẹ, niṣe lo pariwo nigba to ri i pe fọto naa jọra, bọwọ ṣe tẹ wa niyẹn.”

Awọn ọlọpaa ni ogbologboo onijibiti ni Olumide yii, wọn ni ẹrọ kan (app) wa lori foonu ẹ to maa n pese atẹjiṣẹ banki eyikeyii ti wọn ba fẹẹ lo, to si maa jọra gẹlẹ bii atẹjiṣẹ ojulowo.

Wọn ni iwadii ṣi n tẹsiwaju lori ọrọ wọn.

Leave a Reply