Oluranlọwọ ni Qudus tawọn ọlọpaa yinbọn pa n’Ibadan jẹ fun wa – Awọn obi Qudus

Ọlawale Ajao, Ibadan

Awọn obi Agbọlade Abdul Qudus, ọmọọdun mẹẹẹdogun ti ọlọpaa yinbọn pa n’Ibadan lọsẹ to kọja ti ṣapejuwe ọlọpaa to huwa ika naa gẹgẹ bii ọdaju eeyan to sọko ibanujẹ ayeraye sinu idile awọn nitori alaaanu ati oluranlọwọ lọmọ naa jẹ ninu idile naa.

ALAROYE gbọ pe lasiko ti ọmọdekunrin naa n lọ sibi iṣẹ lọlọpaa kan deede yibọn fun un, to si ku loju ẹsẹ.

Awọn ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju wọn, ti wọn ba akọroyin wa sọrọ lori iṣẹlẹ yii to mẹfa, gbogbo wọn ni wọn sọ pe ṣadeede lawọn ri i ti ọlọpaa kan to n jẹ Sunday na ibọn si Abdul Qudus, awọn si ri i ti ọmọ naa n bẹ ẹ bo tilẹ jẹ pe awọn ko mọ ohun to pa wọn pọ, ṣugbọn nigbẹyin, ọlọpaa yii papa yinbọn fun ọmọ naa nigbaaya lẹẹmeji, ọmọ naa si ṣubu lulẹ lẹsẹkẹsẹ, o dagbere faye.

Ṣugbọn ṣaaju la gbọ pe awọn ọmọ iṣọta to dara pọ mọ awọn to n ṣewọde lati jẹ ki ijọba ṣatunṣe si awọn nnkan kan ti ko lọ deede laarin ilu ti kọ lu agọ ọlọpaa to wa l’Ọjọọ, n’Ibadan, pẹlu bi wọn ṣe n lẹ oko nla nla mọ awọn agbofinro ninu teṣan wọn. Boya ara awọn oluwọde to n lẹ̀kò yii lọkunrin agbofinro naa pe ọmọ ẹkọṣẹ yii, ko sẹni to le sọ.

Ati Abdul Qudus, ati Sunday ti ọrọ ọhun kan gbọgbọn, ko si ẹnikankan laye ninu wọn lati ṣalaye ohun to ṣẹlẹ gan-an laarin wọn. Idi ni pe ko ju wakati meji lọ ti awọn ọdọ tinu n bi fi lọọ pa Sunday naa mọ ọfiisi ẹ, ti wọn si dana sun teṣan ọlọpaa mejeeji to wa l’Ọjọọ pẹlu mọto bii ogun to wa nibẹ.

ALAROYE ṣabẹwo si ile awọn ọmọdekunrin ti wọn yinbọn pa yii laduugbo Temidire, n’Iyana Bodija, n’Ibadan, iya ọmọ naa, Abilekọ Sherifat Agbọlade, ṣalaye pe “Abdul Qudus ṣẹṣẹ pari idanwo juniọ wayẹẹki ni, esi idanwo rẹ ko si ti i jade.

“O maa n lọ sibi iṣẹ lopin ọsẹ ati nigba to ba ti sukuu de.  Aadọjọ Naira (N150) la maa n fun un lati fi wọ mọto lọ, ọga ẹ lo maa n fun un lounjẹ ọsan atowo ọkọ to maa wọ wale nitori o ti mọ pe kọndiṣan ta a wa lagbara, o waa duro gẹgẹ bii pe oun loun bi i.

“Ọmọ mi ki i ṣe onijangbọn ọmọ. Mọniya to ti n kọṣẹ wẹ́dà lo n lọ laaarọ ọjọ yẹn ti wọn fi yibọn pa a. Gaari ta a fi tẹba ku lalẹ ana lo bu sapo lọ sibi iṣẹ. Gaari ati ẹpa yẹn pẹlu ṣenji to ku lẹyin to ra ẹpa tan ni wọn ba ninu apo ẹ nigba to ku yẹn.

“Ọga ẹ ti kọkọ pe mi pe awọn ko ma ri Abdul Qudus.  Lẹyin naa lawọn eeyan naa n pe mi pe ṣe mo ri i ko too di pe a gbọ pe ráyọ́ọ̀tì ṣẹlẹ l’Ọjọọ. Awọn ti wọn da a mọ ti wọn ri fọto rẹ lori intanẹẹti ni wọn waa tufọ iku ẹ fun wa ni nnkan bii aago mẹfa n lọọ lù nirọlẹ.”

Ninu ọrọ tiẹ, baba oloogbe, Ọgbeni Hmmed Agbọlade, ẹni to rọ ijọba lati fopin si ipakupa ti awọn ọlọpaa maa yinbọn pawọn alaiṣẹ nilẹ yii, ṣapejuwe ọmọ ẹ ti wọn pa yii gẹgẹ bii oluranlọwọ idile wọn.

Gẹgẹ bi ọkunrin ọlọkada naa ṣe sọ, “Ẹlẹtiríṣíàn ni mi tẹlẹ, nigba ti nnkan ko jọra wọn nibẹ ni mo di ọlọkada to  n na agbegbe Baṣọrun (n’Ibadan).

“Abdul Qudus jẹ ọmọ to laaanu, oluranlọwọ lo jẹ fun mi. Ọpọ igba ti nnkan ko ba fẹẹ to ninu ile, boya a tẹba, ko sẹran tabi ẹja ta a fi maa jẹ ẹ, oun ni ma a pe, a a si sọ pe ‘dadi mi, o ya, ẹ gba igba naira yii ka fi ra ẹja’ nitori o ti n ri tọrọ kọbọ nibi iṣẹ wẹ́dà to n kọ. Ti mo ba pe e pe Abdul Qudus, o ya jẹ ka jọ ṣe nnkan bayii o, gbogbo ọna lo maa gba ran mi lọwọ. Ki i fa ijagbọn, ọmọ daadaa ni.

“Ijọba ni iṣẹ pupọ lati ṣe. Mo rọ ijọba lati fopin si ipaniyan. Ofin wà, ẹ jẹ ka ṣe ohun gbogbo pẹlu ofin. Ibọn ti wọn gbe fọlọpaa, ki i ṣe pe lati pa araalu bi ko ṣe lati fi daabo bo wọn atawọn funra wọn naa. Mo rọ ijọba lati fopin si aṣilo agbara awọn ọlọpaa ati bi wọn ṣe maa n yinbọn pa awọn alaiṣẹ eeyan yii.

“A dupẹ lọwọ awọn to fi iṣẹ tiwọn silẹ ti wọn n daamu kiri lati ri i pe wọn sinku ọmọ mi nitori emi paapaa ko le ṣeto bi wọn ṣe ṣe lati ri i pe a ri oku ẹ sin.”

Lọsan-an ọjọ keji, iyẹn Ọjọruu, Wẹsidee, to kọja, ni wọn sinku Abdul Qayum si itẹ oku awọn Musulumi to wa niluu Lalupọn, nitosi Ibadan.

Leave a Reply