Oluwo fẹẹ ṣepade apero laarin Fulani darandaran atawọn agbẹ 

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Lati le fopin si wahala to n ṣẹlẹ kaakiri orileede Naijiria laarin awọn agbẹ atawọn Fulani darandaran, Oluwoo tilu Iwo, Ọba Adewale Akanbi, ti pepade apero, eleyii ti yoo waye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.

Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin Oluwoo, Alli Ibraheem, fi ṣọwọ s’ALAROYElo ti sọ pe eredi ipade apero naa ni lati ri i pe alaafia jọba laarin wọn.

O ṣalaye pe inu gbọngan nla inu aafin Oluwoo ni yoo ti waye.

Alli ṣalaye pe Kọmiṣanna fọrọ agbẹ l’Ọṣun, Ọgbẹni Adewọle Adedayọ, ni yoo jẹ alaga ipade apero naa, wọn ṣi n reti awọn ori-ade, awọn baalẹ ilu Iwo, awọn agbẹ atawọn Fulani darandaran nibẹ.

Leave a Reply