Aderouonmu Kazeem
Fọto kan lawọn eeyan ri lori fesibuuku nibi ti Kabiyesi Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Abdul Rasheed Adewale Akanbi, tiw aninu aṣọ alarabara kan, aṣọ naa jọ aṣọ awọn aladura Kristẹni pupo, bẹẹ lo tu nfẹgbe ka njọ aṣọ awọn alaafaa. Loju-ẹsẹ lawọn eeyan ti bẹrẹ si kọ oriṣiriṣi ọrọ si abẹ fọto ọba alaye naa, bi awọn kan si ti n kan saara si i, bẹẹ lawọn eeyan pupọ n bu u.
Ṣaaju asiko yii ni Kabiyesi ti sọ pe ki wọn maa pe oun ni alayeluwa mọ, Emir, iyẹn orukọ tawọn ọba alahusa n jẹ ni ki wọn maa pe oun.
Nigba tawọn eeyan wa ri fọto ti Oluwoo tun mura bii baba aladura yii, o fẹ ma si ohun kan bayii tawọn eeyan ko sọ si ọba alaye naa tan, o si jọ pe, pupọ ninu awọn eeyan ọhun ni imura naa ko dun mọ.
Ohun tawọn kan tiẹ n sọ ni pe, imura naa ko ba ori ade mu rara, nitori o ni irufẹ aṣọ ti ọba alaye gbọdọ maa wọ nilẹ Yoruba.
Ọjọ kọkandinlogun oṣu kọkanla ọdun 2015, ni Ọba Abdul Rasheed Adewale Akanbi gbade gẹgẹ bi Oluwo kerindinlogun to maa jẹ nilẹ Iwo olodo Ọba. Nigba to si di inu oṣu kin-in-ni ọdun 2016 ni wọn fun un lọpa aṣe.
Ilu oyinbo lọhun-un ni kabiyesi yii n gbe ko too wale waa jọba.
Lasiko igba kan, ọpọ igba ni iroyin nipa ọba alaye yii maa n gba igboro kan, awọn iroyin to si maa n jade nipa ọba yii, a maa yani lenu pupọ. Lara eyi tawọn eeyan ko ni i tete gbagbe ni ti ọba alaye ẹgbẹ ẹ kan ti wọn sọ pe Oluwo kan lẹṣẹẹ nibi ipade lọbalọba.
O fẹẹ jọ pe, iṣẹlẹ yii lo mu ariwo nipa Oluwo sinmi diẹ, nitori fun igba pipẹ lawọn eeyan ko fi bẹẹ gburoo ọba alaye naa, bẹẹ lawọn ọba alaye nipinlẹ Ọṣun paapaa gbe igbẹsẹ lori iwa ọhun.
Tẹ o ba gbagbe, Olori kabiyesi yii naa ti figba kan gba ileeṣẹ tẹlifiṣan ori afẹfe kan lọ, nibẹ lo ti tu awọn aṣiri majẹkayegbọ sita nipa Oluwo, latigba naa si ni ariwo ti lọlẹ patapata nipa Ọba alaye yii, ki ọrọ fọto too tun gba igboro kan bayii.