Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ko sẹni to mọ arojinlẹ ti Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi, ro to fi bọ sori ẹrọ ayelujara lati ṣe yegede awọn to jẹ ọta rẹ.
Gẹgẹ bi nnkan ti Ọba Akanbi kọ sibẹ, “Awọn ọta mi ti pofo, mo si yayọ iṣẹgun lori wọn. Eyi ni oju ọba to bori gbogbo awọn ọta rẹ, to fi mọ eyi to n sun lori ibunsun mi, to bimọ fun mi, to fi majele sounjẹ fun mi, to gba owo lati gbẹmi mi, to n ka fọnran gbogbo irinajo mi silẹ ninu ibunsun ati ninu aafin fun odidi ọdun mẹrin.
“Ibaṣepọ alaparutu, ẹni to n beere owo pe ki oun le panu mọ nipa aṣiri mi, ṣugbọn ti ko ri eepinni gba bii ọmọbinrin ara India to jẹ ojulumọ Oloye Fẹmi ti Toronto lọdun 2017, ṣugbọn aṣiri kan ti wọn ko mọ nipa mi ni agbara ati ipa Ọlọrun Olodumare, ẹni ti gbogbo iyin yẹ, ti ko si ni i fi ẹni tiẹ silẹ fun ọta lati fi ṣe ẹlẹya.
“Awọn ọba, koda, awọn ayederu ọba nla nla, awọn eeyan loriṣiiriṣii, awọn ọta bii ọrẹ, kora wọn jọ lodi si mi, ṣugbọn lorukọ Olodumare, o ran mi lọwọ lati ba ti wọn jẹ, emi si wa digbi ni gbogbo ọjọ, gbogbo igba, wakati, iṣẹju ati aaya kọọkan ninu agba Olodumare.
“Wọn ṣi maa ba ijakulẹ pade. Bawo lẹ ṣe n ṣe pẹlu igbesi aye itiju ti ẹ n gbe bayii? Hahahaha”