Oluwoo fẹẹ ṣe ayẹyẹ ‘Ọdun Ọlọrun’ ninu oṣu kọkanla

Florence Babaṣọla

Lati fi imọriri han si iṣẹ agbara Ọlọrun, Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ti kede ọjọ kẹsan-an, oṣu kọkanla, ọdun yii, gẹgẹ bii ọjọ lati ṣe ayẹyẹ “Ọdun Ọlọrun”.

Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin rẹ, Alli Ibaheem, fi sita lo ti sọ pe iyin si Ọlọrun nikan ni wọn yoo fi ọjọ naa ṣe.

O ni ayẹyẹ naa yoo jẹ ipejọpọ gbogbo awọn eeyan lai fi ti ẹsin tabi ẹya ṣe rara, bi ko ṣe lati fi imọriri Ọlọrun han fun aabo, aanu, ipese, itọni ati agbara rẹ lai ka gbogbo laasigbo to n doju kọ aye lọwọlọwọ ṣi.

Alli ṣalaye pe bi Musulumi ṣe n ṣayẹyẹ ọdun itunu aawẹ ati Ileya, ti awọn Kristiẹni naa si n ṣe ọdun Keresimesi, naa ni Oluwoo, gẹgẹ bii baba fun gbogbo awọn aṣaaju, ti ko si si ninu ẹgbẹ okunkun, ṣe ṣagbekalẹ eto naa.

Gẹgẹ bo ṣe wi, o tọ lati fi imọriri han si Ọlọrun to da eniyan latinu erupẹ, to si fun wọn lagbara lati jọba lori ohun gbogbo to ku to da, to si tun lagbara lati pa ọkan ati ẹmi mọ.

O ni ko si nnkan miiran ti wọn yoo ṣe lọjọ naa ju iyin ati ọpẹ si Ọlọrun lọ nitori Oun nikan ni gbogbo ọpẹ tọ si.

Leave a Reply