Oluwoo ki i ṣe apẹẹrẹ ọba ilẹ Yoruba to ṣee mu yangan, wọn ko ba Ifa sọrọ ki wọn too yan an- Ẹlẹbuubọn

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Araba tilu Oṣogbo, Oloye Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn, ti sọ pe ti wọn ba n wa ọba kan ti ko ni oye kankan rara nipa aṣa ati iṣe ilẹ Yoruba to ti jọba, Oluwoo tilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Akanbi, ni.

Nitori naa ni agbarijọpọ awọn oniṣẹṣe labẹ Iṣọkan Ọrunmila ṣe kilọ fun Ọba Akanbi lati jawọ ninu awọn iwa titẹ aṣa Yoruba mẹrẹ ko ma baa kandin ninu iyọ.

Lasiko ipejọpọ ọlọjọ kan ti wọn pe ni ‘Ofa Unity Conference’, eyi to waye niluu Oṣogbo laipẹ yii ni Oloye Ẹlẹbuibọn ti sọ pe ko si ọba ti ko ni nnkan an ṣe pẹlu aṣa Yoruba, nitori Ifa lo n yan ọba sipo.

O ni Oluwoo ki i ṣe apẹẹrẹ ọba ilẹ Yoruba to ṣee muyangan nitori wọn ko ba Ifa sọrọ ki wọn too yan an le awọn ara ilu rẹ lori. O ni eleyii si ti mu ifasẹyin nla ba ipo ori-ade ilu Iwo latigba to ti debẹ.

Gẹgẹ bo ṣe wi, gbogbo ilu nilẹ Yoruba ni wọn ni iledii (seclusion room), nibi ti wọn maa n fi ẹni ti Ifa ba mu pe ko jọba pamọ si fun iwọn ọjọ diẹ, nibẹ naa ni yoo si ti kọ nipa aṣa ati iṣe ilẹ Yoruba, ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe Oluwoo ko lanfaani si iru igbesẹ bẹẹ.

Fun un lati maa ṣiwa-hu nipasẹ ọlaju, Baba Ẹlẹbuibọn sọ pe eleyii fi han gbangba pe aaye nla ṣi silẹ niluu Iwo. O ni “O ṣee ṣe ko jẹ pe gbogbo awọn afọbajẹ atawọn ijoye ibẹ ti di Musulumi tabi Kristiẹni tan.

“O tun n fọwọ sọya pe gomina kan lo sọ oun di ọba, ki i ṣe Ifa, o daju pe idi niyẹn to fi n huwa bo ṣe n huwa. Ara awọn ipenija ti ọlaju ati ẹsin ilẹ okeere mu ba ipo lọbalọba nilẹ Yoruba niyẹn, paapaa, bi awọn ti a gbe aṣa le lọwọ gan-an ṣe ti n ku.

“Ko si ifagba-fun-agba mọ laarin awọn lọbalọba, o si gbọdọ jẹ ojuṣe gbogbo eniyan bayii lati da iyi ati ẹyẹ aṣa wa pada. Ki awọn ọba mọ ojuṣe wọn, ki awọn ijoye naa si mọ aaye wọn lai fi ti ẹsin ajeji ṣe rara”

Ṣaaju ni Araba Agbaye, Owolabi Aworeni ti kilọ fun Oluwoo lati dẹkun fifẹnu yẹpẹrẹ aṣa Yoruba nitori atubọtan iru iwa bẹẹ.

O ni o ti n di gbọnmọ-gbọnmọ Ọba Akanbi to jẹ pe to ba ti fẹnu saata aṣa Yoruba tan nita gbangba ni yoo maa bẹbẹ kaakiri.

Leave a Reply