Oluwoo n wa Hassan Lawal, o ni ẹbun owo nla wa fẹni to ba ri i

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ti kede pe ẹnikẹni to ba ba oun ri ọmọkunrin kan torukọ rẹ n jẹ Hassan Lawal, yoo gba ẹbun ẹgbẹrun lọna aadọta Naira.

Omo agboole Bello, niluu Iwo, ni wọn pe Hassan.

Gẹgẹ bi atẹjade ti Ọba Akanbi funra rẹ fọwọ si to tẹ ALAROYE lọwọ ṣe ṣalaye, o ti pẹ ti Hassan ti n da wahala silẹ niluu naa, to si n da omi alaafia gbogbo agbegbe to ba de ru.

Oluwoo sọ siwaju pe laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejila, oṣu Keji, ọdun yii, lo deede bẹrẹ si i ṣa awọn eeyan ti wọn n lọ jẹẹjẹ wọn ladaa. Lai ṣẹ-lai ro la gbọ pe Hassan kọju ija si awọn eeyan ilu Iwo, to si ti di gbogbo igba fun un lati maa huwa ibajẹ yii. Niṣe ni wọn ni o ṣa awọn eeyan naa yannayanna.

Ọba Akanbi tẹ siwaju pe ikoko ko ni i gba omi, ko tun gba ẹyin, ko tun gba sọṣọ inu ẹ fun awọn ole, janduku atawọn ajagungbalẹ niluu Iwo, nitori eyi ti ọwọ ba tẹ ninu wọn ko ni i lọ lai jiya.

 

Leave a Reply