Oluwoo to n foju tẹnbẹlu iṣẹṣẹ Yoruba n kọ lẹta si ibinu awọn irunmọlẹ-Ọba Ogboni

Ọlawale Ajao, Ibadan

Aarẹ ẹgbẹ awọn oniṣẹṣe nipinlẹ Ọṣun, Ọmọwe Oluṣeyi Atanda, ti ṣapejuwe Oluwoo tilẹ Iwo, Ọba Abdul Rasheed Adewale (Tèlú 1) gẹgẹ bii ọba ti ko ka iṣẹṣe si, to si ṣee ṣe ko rija awọn igba irunmalẹ.

Nitori ipo ti Ọba Adewale to awọn oriṣa si lasiko to ṣọdun Olodumare niluu Iwo lọjọ kẹsan-an, oṣu kọkanla, ọdun 2021 yii, ti i ṣe ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja.

Ta o ba gbagbe, ninu Ọdun Olodumare ọhun, eyi ti wọn ṣe laafin Oluwoo, lati fọpẹ ati iyin fun Ọlọrun, Olodumare  l’Ọba Adewale ti sọ pe ipo oun gẹgẹ bii ọba ga ju ipo oriṣa lọ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Arole Ọlọrun lorilẹ aye ati alaṣẹ lori oriṣa l’Ọlọrun ṣe awa ọba. Bi eeyan ba jẹ igbakeji oriṣa, oriṣa ni yoo maa ran iru ẹni bẹẹ niṣẹ nitori oriṣa lọga ẹ.

“Nibi ti mo si ba a de yii, emi kọja ẹni to tun le ṣe igbakeji, nitori naa, alaṣẹ lori oriṣa lemi, mi o ki i ṣe igbakeji oriṣa. Ojo pa bata pa jinwinjinwin ẹni to ba pe mi nigbakeji oriṣa.”

Ipo ti Oluwoo to awọn oriṣa si yii ko dun mọ awọn oniṣẹṣe ninu, paapaa pẹlu bi ọba naa ko ṣe pe awọn ẹlẹsin ibilẹ sibi ayẹyẹ alarinrin naa, to jẹ pe kikidaa awọn Musulumi atawọn Krisitiẹni ni wọn da ṣọdun Olodumare laafin ọba.

Ṣugbọn bi wọn ko ṣe fun awọn ẹlẹsin ibilẹ ni ipa kankan ko nibi ajọdun naa ko dun aarẹ awọn oniṣẹṣe bii ipo giga ti ọba naa gbe ara rẹ ga ju awọn oriṣa lọ.

Nigba to n ba ALAROYE sọrọ lẹyin eto naa, Ọmọwe Atanda, to tun jẹ Ọba Ogboni igba iwasẹ nipinlẹ Ọṣun, sọ pe ‘Ọba Adewale yo tan, o n wa bẹkunbẹkun kiri. Ki lo de to fi ni ki wọn ma pe ọba nigbakeji oriṣa?

“O n fẹnu tẹnbẹlu awọn oriṣa ni. Awọn igba irunmalẹ si n wo o pe ko ti i to asiko ti awọn maa mu un ni.”

Leave a Reply