Omi ma ti fẹẹ gbe wọn lọ ni Lafiagi

Stephen Ajagbe, Ilorin

Emir ilu Lafiagi, nijọba ibilẹ Edu, nipinlẹ Kwara, Alhaji Saadu Kawu Haliru, atawọn araalu naa lapapọ ti kegbajare sijọba apapọ ati ipinlẹ lati dide iranlọwọ fun wọn lori iṣẹlẹ omiyale to maa n waye lọdọọdun.

Alhaji Haliru to sọrọ lorukọ gbogbo araalu rawọ ẹbẹ naa lasiko ti Igbakeji gomina Kwara, Ọgbẹni Kayọde Alabi, pẹlu awọn ikọ to ko sodi lọọ ṣe abẹwo sawọn ti iṣẹlẹ omiyale ti ba nnkan oko wọn jẹ, to si tun sọ di alaini ile lori niluu Lafiagi lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.

O rọ ijọba lati ko awọn to n gbe lawọn agbegbe tiṣẹlẹ omiyale ti n ṣẹlẹ kuro patapata lọ si ibomin, paapaa bi ajọ to n wo oju ọjọ, NIMET, ti ni Kwara wa lara awọn ipinlẹ tiṣẹlẹ omiyale yoo ba finra lọdun yii.

Ọkan lara awọn ti omiyale n da laamu labule Chewuru, ni Lafiagi, Saliu Umoru, ni awọn ṣetan lati fi ibi tawọn n gbe silẹ kawọn si maa fi ibẹ da oko lati lọ maa gbe  lori oke.

O ni ijọba nikan lo le ran awọn lọwọ lati pese ibugbe mi-in fawọn.

Igbakeji Gomina, Kayọde Alabi, fi ọkan awọn tiṣẹlẹ omiyale naa ba dukia wọn jẹ balẹ pe ijọba yoo ran wọn lọwọ laipẹ.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

2023: Ẹgbẹ TOTT rọ Tinubu atawọn oludije yooku lati panu pọ gbe Ọṣinbajo kalẹ

Ọrẹoluwa Adedeji Ẹgbẹ kan, The Ọsinbajo Think Tank (TOTT), ti parọwa si aṣaaju ẹgbẹ oṣelu …

Leave a Reply

//zikroarg.com/4/4998019
%d bloggers like this: