Omiyale ṣọṣẹ l’Oṣogbo, eeyan mẹta lo ku, ọpọlọpọ dukia lo si ṣofo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Lasiko ti a n koroyin yii jọ, o kere tan, oku eeyan mẹta ni wọn ti ri yọ ninu odo niluu Oṣogbo ati ilu Ẹrin-Ọṣun, ti ọpọlọpọ awọn ti wọn nile nitosi odo atawọn oniṣọọbu ko si lee sọ iye nnkan ti wọn padanu sinu omiyale to ṣẹlẹ lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.

Odidi wakati mẹrin ni ojo nla naa fi rọ, ọwọ-alẹ lo si bẹrẹ, koda, gbogbo fẹnsi ile ijọba ipinlẹ Ọṣun ni Oke-Fia lo wo lulẹ bẹẹrẹbẹ.

Ni awọn agbegbe bii Rasco, Ọbatẹ, Atimọwa, Oke Ayepe, Oke Ijẹtu, Ita Olookan ti ALAROYE de, ọṣẹ nla ni omiyale naa ṣe.

Ni ọja Akindẹkọ, asun-un-dakẹ ẹkun lawọn ọlọja ti omiyale naa wọnu ṣọọbu wọn n sun, gbogbo ọja wọn, to fi mọ irẹsi, ẹwa, sẹmo, filawa, ọṣẹ ifọṣọ, ẹgusi, elubọ, gaari ati bẹẹ bẹẹ lọ lagbara ojo wọ lọ sinu odo nla to wa nitosi ibẹ.

Ọpọlọpọ ile to wa lẹgbẹẹ odo Ita-Olookan ni omiyale fọwọ kan, bi awọn abala kan ṣe wo lulẹ ni a ri i ti awọn mi-in n sa aṣọ atawọn nnkan eelo inu ile sita.

Lẹyin ti omi fa diẹ loju odo Oke-Ayepe ati ti Oke-Onitii lọsan-an Ọjọruu, Wẹsidee, la gbọ pe wọn ri oku awọn eeyan meji ti wọn lefoo tente, bẹẹ naa si lawọn olugbee Ẹrin-Ọṣun sọ pe wọn ri oku ẹni kan gbe jade ninu odo ibẹ.

Gẹgẹ bi ọkunrin kan to ba wa sọrọ ni Oke-Ayepe, Bọlarinwa, ṣe wi, aarin igi ọpẹ meji ninu odo Ọkọọkọ to kọja lagbegbe naa ni wọn ti ri oku obinrin kan to n mi dirodiro, ti wọn si ke si awọn agbaagba adugbo lati mọ ohun ti wọn yoo ṣe lori ẹ.

O fi kun ọrọ rẹ pe awọn araadugbo ranṣẹ si awọn oṣiṣẹ sifu difẹnsi ti ọfiisi wọn ko jinna sibẹ, awọn yẹn ni wọn si gbe oku naa. O ni awọn mọlẹbi obinrin ọhun gan-an ti yọju.

Ọkunrin kan to n gun ọkada rẹ lọ sile ni Ẹrin-Ọṣun la gbọ pe o ko sinu odo Oke Awesin, lasiko ti ojo nla naa n rọ, ọsan Ọjọruu ni wọn si too ri oku rẹ fa yọ.

Inurin ti Ẹrin Ọṣun, Oloye Ọlawuyi Adeleke, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni yatọ si ọkunrin to ku ọhun, ko si ibi ti omiyale ti ṣọṣẹ niluu Ẹrin Ọṣun.

Ṣe lagbara ojo bo ori afara oju-ọna Aṣoju Ọba si Awoṣuuru lọ patapata, ti ko si sẹni to le kọja nibẹ, ironu si dori gbogbo awọn ti wọn ni sọọbu lẹgbẹẹ odo naa kodo.

Ninu ọrọ tirẹ, Alukoro fun ajọ sifu difẹnsi l’Ọṣun, Daniel Adogun, fidi rẹ mulẹ pe oku eeyan meji ti wọn ko sinu agbara ojo naa lawọn ri fa yọ lonii.

Bakan naa, ninu atẹjade kan ti kọmiṣanna feto iroyin ati ilanilọyẹ nipinlẹ Ọṣun, Funkẹ Ẹgbẹmọde, fi sita, o ni ijọba ti n ṣagbeyẹwo ipa ti omiyale naa ni lori awọn araalu kaakiri ibi to ti ṣẹlẹ, nitori naa, ki gbogbo wọn ṣe ṣuuru.

Ẹgbẹmọde sọ pe laipẹ nijọba yoo gbe igbesẹ lati fopin si wahala omiyale naa, o si tun rọ awọn araalu lati dẹkun dida idọti soju ibi ti agbara ojo n gba kọja.

Leave a Reply