Ọmọ Adedoyin lo ṣeto bi wọn ṣe gbe oku Timothy lọ sinu igbo-Ọlọkọde

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, Ọlawale Ọlọkọde, ti sọ pe ọkan lara awọn afurasi ti ọwọ tẹ lori ọrọ iku Timothy to jẹ akẹkọọ Fasiti OAU, ti jẹwọ pe ọmọ ẹni to ni otẹẹli naa, Roheem Adedoyin, lo ṣeto bi awọn ṣe gbe oku ọkunrin naa lọ sinu igbo.

Ọlọkọde ṣalaye pe Roheem Adedoyin ni oludari ileetura naa, oun lo si lẹdi apo pọ mọ awọn oṣiṣẹ kan lati lọọ sin Timothy sinu igbo lai sọ fun awọn ọlọpaa.

Lasiko to n kopa nibi eto ori redio kan niluu Oṣogbo ni kọmiṣanna ọlopaa ti sọ pe Roheem ti sa lọ patapata, lasiko iwadii awọn ọlọpaa ni aṣiri ibi ti wọn sin in si tu.

O fi kun ọrọ rẹ pe ọmọkunrun yii ati meji lara awọn manija ileetura naa ni wọn gbe oku Timothy jade, ti wọn si lọ sin in.

Ọlọkọde sọ siwaju pe ko sẹnikankan to fi ọrọ naa to awọn agbofinro leti titi di igba ti wọn kede pe wọn n wa ẹnikan, ti awọn ẹka to n ri si ọrọ ijinigbe si bẹrẹ iṣẹ titi ti aṣiri fi tu pe o gba yara ninu otẹẹli yẹn. Ninu iwadii wọn ni wọn ti mọ ibi ti wọn sin in si, ti wọn si lọọ hu oku rẹ jade.

Nipa ti fọnran kan to n lọ kaakiri ori ẹrọ ayelujara, nibi ti Dokita Ramon Adedoyin ti n sọ pe oun ki i ṣe apaniyan, Ọlọkọde sọ pe oun ko mọ bo ṣe jẹ ati pe oun ko mọ ibi to ti ṣe fọnran ọhun.

O ni ki awọn araalu farabalẹ ki esi ayẹwo ti awọn akọṣẹmọṣẹ ṣe si oku Timothy jade nitori eyi ni yoo sọ ni pato, iru iku to pa a.

Ninu iroyin miiran, aago mẹta ọsan ọjọ Aje ni wọn bẹrẹ ayẹwo si oku oloogbe nileewosan UNIOSUN Teaching Hospital, eyi ti wọn n pe ni LAUTECH tẹlẹ, nnkan bii aago mẹfa aabọ ni wọn si too ṣetan nibẹ.

Ni bayii, gbogbo aye lo n duro de ohun ti yoo jẹ abajade ayẹwo ọhun.

 

Leave a Reply