Ọmọ ẹgbẹ onimọto ti wọn pa nibi ija awọn oloṣelu da ibẹru-bojo silẹ l’Ekiti

Taofeek Surdiq,
Ado-Ekiti
Ibẹru ati ipaya lo gba ọkan gbogbo olugbe ilu Ado-Ekiti, lọjọ Aiku, Sannde, nigba ti awọn eeyan gbọ pe ẹgbẹ onimoto ti kora wọn jọ lati lọọ gbẹsan iku ọmọ ẹgbẹ wọn ti wọn pa nibi ija awọn ẹgbẹ oṣelu to waye ni Itaji-Ekiti.
Tọpẹ Ajayi ti wọn pa yii jẹ ọmọ ẹgbẹ onimoto Road Transport Employer Association (RTEAN), to si tun jẹ alatilẹyin ẹgbẹ Onigbaalẹ (APC).
Ajayi ni wọn pa ni Itaji-Ekiti, nigba ti awọn ẹgbẹ APC ati ẹgbẹ Ẹleṣin ja lakooko ti awọn ẹgbẹ mejeeji yii n ṣe ipolongo wọn ni ilu naa.
Bi okiki iku rẹ ṣe kan ka gbogbo ipinlẹ naa ni awọn ọmọ ẹgbẹ onimọto Roodu yii ti ko ara wọn jọ lati lọọ ṣe akọlu miiran sawọn ọmọ ẹgbẹ Ẹleṣin, pẹlu bi wọn ṣe gbegi di awọn ọna kọọkan to wọ ipinlẹ naa.
Eleyii lo ba awọn eeyan lẹru, to si da jinnijinni silẹ nigba ti awọn eeyan to fẹẹ lọ sile ijọsin dari pada sile, ti gbogbo popo ati adugbo si dakẹ rọrọ.
Nigba ti akọroyin ALAROYE de awọn adugbo bii Ekute, ni Ado-Ekiti, awọn ọlọkada ati awọn awakọ takisi ati awọn awakọ aladaani ni wọn n ṣẹri pada, nigba ti wọn ri i pe awọn ọmọ ẹgbẹ onimoto naa ti kora wọn jọ si oju popo.
Ẹyin eyi ni awọn sọja, ati awọn ọlọpaa kogberegbe, awọn sifu difẹnsi tete gba awọn adugbo kọọkan niluu Ado-Ekiti, lati dẹkun awọn ọmọ ẹgbẹ onimoto naa.
Ni kete ti awọn ẹṣọ alaabo yii gba oju popo, ti wọn si n rin kaakiri pẹlu ọkọ akọtamin wọn ni alafia bẹrẹ si i jọba pada ni awọn adugbo kọọkan.
Ọkọ akọtamin mẹta to jẹ ti awọn ọlọpaa ati ti awọn ṣọja ni wọn gbe si awọn adugbo bii Atikankan, Ajilosun, Ijigbo, garaaji Tosin Aluko ati awọn adugbo miiran.
Nigba to n sọrọ lori ọrọ naa, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, sọ pe awọn ọlọpaa ti mu gbogbo ijaya naa wa silẹ pẹlu bi wọn ṣe pin ara wọn si gbogbo igboro.
O fi kun un pe Kọmisana ọlọpaa, Ọgbẹni Morounkeji Adesina, ti paṣẹ pe ki wọn kọ awọn ọlọpaa kogberegbe lọ si awọn adugbo kọọkan to wa ni Ado-Ekiti lati da rogbodiyan ati wahala duro.

Kọmisana naa sọ pe awọn ọlọpaa ati awọn agbofinro miiran ti n ṣe ohun gbogbo lati ri i pe eto idibo to n bọ lọna lọsẹ yii waye nirọwọrọsẹ.
O fi kun un pe kọmiṣanna naa ti paṣẹ pe ki iwadii bẹrẹ lori iku onimọto naa, ati pe ẹni ti aje iṣẹlẹ naa ba ṣi mọ lori gbọdọ fi oju wina ofin.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//lephaush.net/4/4998019
%d bloggers like this: