Ọmọ ẹgbẹ PDP meje ku ninu ijamba ọkọ nigba ti wọn n bọ lati ibi ipolongo ibo wọn 

Jọkẹ Amọri

Ajalu nla lo ṣẹlẹ ninu ẹgbẹoṣelu PDP pẹlu bi meje ninu awọn ọmọ ẹgbẹ naa ṣe ku, ti awọn bii mejilelogun si fara pa yanna yanna, ninu ijamba ọkọ kan to waye ni oju ọna Panyam, to wa nijọba ibilẹ Mangu, nipinlẹ Plateau, lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrinla, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, nigba ti wọn n bọ lati ibi ipolongo ibo ti wọn lọ.

ALAROYE gbọ pe lasiko ti wọn n ti ibi ipolongo ibo gbogbo agbegbe naa ti wọn lọọ ṣe nijọba ibilẹ Pankshin nijamba naa waye ni abule kan ti wọn n pe ni Jwak, ti ko jinna si ibi ti biriiji kan ti wọn n pe ni Panyam wa, nijọba ibilẹ Mangu.

Ọkọ nla ti wọn gbe lọ fun kampeeni ti awọn ọmọ ẹgbẹ naa si kun inu rẹ bamu lo takiti, nigba ti wọn yoo si fi mọ ohun to n ṣẹlẹ, eeyan meje ti jẹ Ọlọrun nipe, ọpolọpọ si fara pa yanna yanna, bẹẹ lawọn kan wa lẹsẹ-kan-aye ẹsẹ-kan-ọrun lasiko ta a n kọ iroyin yii lọwọ.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, ọkan ninu awọn oludari eto ipolongo fun Atiku\Okowa ni agbegbe naa, Yiljap Abraham, ṣalaye ninu atẹjade to fi sita nipa iṣẹlẹ naa pe ‘‘Wọn ti fidi rẹ mulẹ fun mi pe eeyan meje lo ti padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ naa to waye lọjọ Abamẹta, Satide, si awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu PDP, ẹka ti ipinlẹ Plateau. Ibi eto ifilọlẹ ipolongo gbogbogboo ẹgbẹ wa fun agbegbe naa ti wọn ṣe ni Pankshin, ni wọn ti n bọ, ko too di pe ọkọ nla to ko wọn ni ijamba nibi gẹrẹgẹrẹ to wa laarin Pushit ati Panyam, nijọba ibilẹ Mangu.

‘‘Awọn bii mejilelogun lo fara pa yannayanna, ti wọn si ti ko wọn lọ si ileewosan kan ti wọn n pe ni Nissi Dominion Hospital, to wa ni Mangu. Awọn meji la gbọ pe ijamba ti wọn ni buru ju, bẹẹ ni wọn si ti ṣiṣẹ abẹ fun ẹni kan.

‘‘Wọn ti ko oku awọn to padanu ẹmi wọn yii lọ si awọn ileegbokuu-pamọ-si kan lagbegbe naa’’.

Ninu ọrọ tiẹ, gomina ipinlẹ naa tẹlẹ, to ti tun wa nipo aṣofin agba bayii, Sẹnetọ Jonah Jang, fi ẹdun ọkan rẹ han lori iṣẹlẹ buruku naa. O ni o jẹ ohun to ba ni lọkan jẹ pe awọn eeyan ti wọn lọọ ṣatilẹyin fun ẹgbẹ wọn ni wọn fara pa yanna yanna nibi ijamba yii, ti ẹmi awọn mi-in si ba a lọ.

Jang ni ohun to dun ni jọjọ ninu iṣẹlẹ aburu yii ni pe ọpọ awọn to ba iṣẹlẹ naa rin jẹ awọn ọdọ ti wọn wa ni rewerewe, ti wọn n reti ọjọọla to dara fun ipinlẹ wọn ati orileede Naijiria lapapọ.

Bakan naa lo kẹdun pẹlu gbogbo mọlẹbi awọn to ti ku atawọn to fara pa ninu ijamba naa, bẹẹ lo gbadura fun wọn pe Ọlọrun yoo tete bu ororo itura si oju ọgbẹ naa.Ko sai dupẹ lọwọ gbogbo awọn to ti jade lati sugbaa awọn eeyan yii.

Bakan naa ni oludije sipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu Labour, Dokita Patrick Dakum, ba ẹgbẹ oṣelu PDP kẹdun lori ajalu buruku yii. O kẹdun pẹlu mọlẹbi awọn ti wọn padanu ẹmi wọn pẹlu awọn oludije sipo gomina ati igbakeji lẹgbẹ PDP pẹlu gbogbo ọmọ ẹgbẹ naa lapapọ.

O waa gbadura pe ki Ọlọrun tu awọn mọlẹbi tiṣẹlẹ naa ṣẹlẹ si ninu, ko si fun wọn ni ọkan lati gba iṣẹlẹ naa mọra.

Leave a Reply