Ọmọ ẹlẹ ti mo n fẹ wa ninu oyun, ẹ ba mi bẹ awọn ọlọpaa ki wọn tu mi silẹ – Ogungbe

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ọmọ ogun ọdun ni Samuel Ogungbe, igbo lo n ta ni Mowe, ohun ti wọn tori ẹ mu un lọsẹ to kọja yii niyẹn ti wọn si mu un wa si olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Eleweeran, l’Abẹokuta . Eyi ni alaye ti ọmọ naa ṣe fun AKEDE AGBAYE.

“Igbo ni mo n ta ni Mowe, ọlọpaa waa mu mi lọjọ Mọnde to kọja, nitori wọn ba mi nibi ti mo ti n ta igbo ti wọn dẹ tun ba igbo lọwọ mi.

“Ọndirẹdi naira(N100) ni mo n ta igbo mi, mo dẹ maa n ri  ẹgbẹrun marun-un naira lojumọ, mo maa n dajọ ẹgbẹrun kan tabi meji nigba mi-in ninu owo ti mo n ri. Ko dẹ ki i ṣe pe mo fẹẹ maa tagbo bẹẹ naa o, owo firidọọmu ni mo n wa, nitori mo kọṣẹ bi wọn ṣe n tun ọkada ṣe. Mi o fẹe jale lo jẹ ki n maa lọọ tagbo yẹn, oṣu keji ti mo ti n ta a ree ti mo dẹ n ri nnkan to daa ṣe nibẹ.

“Mo ti f’ọmọ loyun bẹ ẹ ṣe n wo mi yii, ọmọ ẹlẹ ti mo n fẹ ti loyun. Mo nigbagbọ pe mo maa jade nibi, ẹ ba mi bẹ awọn ọlọpaa ki wọn tu mi silẹ, ki n lọ sile lọọ ba iyawo mi’’

Nipa irun buruku to ṣe sori, Samuel to ni ọmọ Ibadan loun, ṣalaye pe irun ọdun loun ṣe. O ni nitori ọdun wa nita loun ṣe kun irun kolokolo toun ṣe sori naa lọda pupa, nitori aṣa to wa nita bayii niyẹn.

Njẹ nibo lo ti n ra igbo to n ta, Samuel sọ pe ẹnikan to n jẹ Joseph lo maa n gbe igbo naa foun. O ni Abẹokuta ni Joseph ti maa n waa ra igbo naa, ati pe ọmọ ẹgbẹ okunkun ni.

Samuel sọ pe, ‘’ Nigba ti Joseph gbọ pe awọn ọlọpaa ti mu mi lo gbe bọdi ẹ, o sa lọ ni tiẹ ni. Wọn o ti i ri i titi di bayii’’

Awọn ọlọpaa ti ni afi ko de kootu laipẹ, nitori oun funra rẹ naa loun mọ pe eewọ ni igbo tita ati mimu ninu ofin ilẹ yii.

 

Leave a Reply