Ọmọ Ibo kan wọ wahala l’Ekiti, obinrin lo ge lọmu jẹ

Aderounmu Kazeem

Nile ẹjọ majisireeti, kan niluu Ado Ekiti, lọkunrin ọmọ Ibo kan ti n ṣalaye ohun to mu un ge ọrẹbinrin ẹ lọmu jẹ lasiko ti ede-aiyede kan waye laarin wọn.

Ẹni ọdun mẹẹdọgbọn ni wọn pe Chibuike Njokwu to ge ọrẹbinrin ẹ lọmu jẹ laduugbo kan ti wọn pe ni Suurulere, lẹgbẹẹ ojuna Basiri, niluu Ado-Ekiti.

Olupẹjọ ọhun lorukọ ijọba, Ọgbẹni Oriyọmi Akinwale, sọ nile-ẹjọ wi pe ̀Ọjọbọ, ọjọ kẹrinlelogun oṣu yii, niṣẹlẹ ọhun waye ni deede aago meje aarọ.

Akinwale sọ pe ọmu to wa lapa osi igbaaya Ifunanya Okonkwo ni ọkunrin yii di eyin mọ, to si bu u wọlẹ daadaa ko too gbe ẹnu kuro laya obinrin to pe ni ọrẹbinrin rẹ yii.

Ọkunrin ọlọpaa yii ni iwa ọdaran gbaa ni Chibuike hu, ati pe o ni ijiya labẹ ofin ipinlẹ Ekiti ti ọdun 2012.

Siwaju si i, o ti bẹ ile-ẹjọ ko fun oun ni anfaani lati tubọ tọpinpin ẹsun ọhun, ati pe oun nilo anfaani lati fi ṣa awọn ẹlẹrii oun jọ lori ẹjọ naa.

Ọkunrin ti wọn wọ lọ sile-ẹjọ yii naa sọrọ niwaju adajọ wi pe oun ko jẹbi rara, bakan naa ni agbẹjọro ẹ, Ọgbẹni Emmanuel Sumọnu, ti bẹ ile-ẹjọ ki wọn fun un ni beeli lọna ti ko ni i ni in lara.

Adajọ ile-ẹjọ Majisireeti ọhun, Arabinrin Adefunkẹ Anoma, ti fun un ni beeli pẹlu ẹgbẹrun lọna aadọta naira ati oniduro.

Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kin-in-ni ọdun 2021, ni igbẹjọ mi-in yoo tun waye.

 

Leave a Reply