Ọmọ iya meji ti rewele o, Taiwo ati Kẹhinde to lu oyinbo ni jibiti ko sọwọ EFCC n’Ilọrin

Stephen Ajagbe, Ilorin

Awọn ọmọ iya meji kan ti rewele bayii o pẹlu bi ọwọ Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati jibiti, EFCC, niluu Ilọrin ṣe tẹ awọn ibeji kan, Taiwo ati Kẹhinde Adebayọ, fẹsun jibiti ori ẹrọ ayẹlujara.

Nibi ti wọn farapamọ si lọwọ ti tẹ wọn l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, lẹyin tawọn kan ta ileeṣẹ EFCC lolobo.

Nigba tawọn oṣiṣẹ EFCC yẹ awọn foonu ati kọmputa alagbeeka ti wọn ba lọwọ wọn wo, wọn ri gbogbo atẹjiṣẹ ti wọn fi ranṣẹ sawọn ti wọn lu ni jibiti lori ẹ.

Laipẹ yii ni wọn yoo foju wọn bale-ẹjọ tiwadii to n lọ ba dopin.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Lanlọọdu ati getimaanu pa ọmọọdun mẹrin, wọn yọ ẹya ara ẹ lati fi ṣoogun owo

Faith Adebọla Diẹ lo ku kawọn araalu tinu n bi dana sun baba getimaanu kan …

Leave a Reply

//ugroocuw.net/4/4998019
%d bloggers like this: