Akolo awọn ọlọpaa Akurẹ, nipinlẹ Ondo, ni ọmọkunrin kan, Sam Ọmọjọla, wa bayii, latari ẹsun ti wọn fi kan an pe o la pako mọ tẹnanti baba rẹ kan lori, o si ṣe bẹẹ ran an lajo aremabọ.
Ba a ṣe gbọ, adugbo kan ti wọn n pe ni Oke-Ijẹbu, niluu Akurẹ, niṣẹlẹ yii ti waye lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, wọn ni ile kan naa ni Alagba Ọmọjọla to jẹ lanlọọdu yii n gbe pẹlu afurasi ọdaran yii ati awọn ayalegbe wọn.
Tẹnanti ti wọn pe ni Baba Ṣẹgun yii ni wọn lo jẹ lanlọọdu naa lowo ile, nigba ti lanlọọdu si sin in lowo naa, ọrọ wọn ko bara mu, lo ba di pe awọn mejeeji n tahun sira wọn. Wọn ni Sam ko si nile lasiko tọrọ yii bẹrẹ.
Lanlọọdu yii ni wọn lo fibinu pe ọmọ ẹ, Sam, lori aago, latari awọn gbolohun kan to sọ pe tẹnanti sọ si i, o lo ri oun fin, oun si fẹ kọmọ naa waa ba oun kilọ fun un.
Ẹnu fa-a-ka-ja-a yii ni wọn wa tọmọ naa fi de, lọmọ naa ba fabinu yọ pe kin ni tẹnanti jẹ yo to fi ri baba oun fin, wọn ni ko beṣu bẹgba, niṣe lo fa pako nla kan tọwọ rẹ to yọ, lo ba la a mọ tẹnanti yii lori, tọun si ṣubu lulẹ bẹẹ.
Awọn aladuugbo sare lati doola ẹmi tẹnanti yii, ṣugbọn wọn ko le gbe e de ọsibitu to fi ta teru nipaa. Kia lawọn ọlọpaa ti de ibi iṣẹlẹ naa nigba ti wọn pe wọn lori aago, wọn si mu afurasi ọdaran ọhun ati baba rẹ lọ sahaamọ wọn, bo tilẹ jẹ pe wọn fi baba naa silẹ lẹyin ti wọn ti gbọ tẹnu ẹ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Ọgbẹni Tee-Leo Ikoro sọ pe iwadii ṣi n tẹsiwaju.