Ọmọ ọdun mẹẹẹdogun dero ẹwọn, nitori akẹkọọ ẹgbẹ ẹ to lu pa l’Abẹokuta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Igbẹjọ waye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrinla, oṣu kẹfa yii, lori ọmọdekunrin kan tọjọ ori ẹ ko ju mẹẹẹdogun lọ, ẹni ti wọn lo lu akẹkọọ bii tiẹ to jẹ obinrin pa, nitori pe o fẹẹ ba a dọrẹẹ, tiyẹn ko gba, iyẹn loṣu keji, ọdun yii.

 Kootu Majisreeti ti ju u sẹwọn oṣu kan gbako titi ti amọran yoo fi ti ọdọ DPP to n gba kootu nimọran wa.

Adajọ Dẹhinde Dipẹolu lo gbọ ẹjọ ọmọkunrin naa, ko gba ipẹ rẹ rara, niṣe lo ni ki wọn gbe e lọ sọgba ẹwọn awọn ọmọde ti wọn n pe ni Boaster, eyi to wa niluu Abẹokuta.

Ohun to ṣẹlẹ gan-an ti ọmọkunrin to jẹ akẹkọọ nileewe Reverend Kuti Memorial Grammar School, l’Abẹokuta, naa fi foju bale-ẹjọ ni pe o nawọ ifẹ sọmọbinrin tọjọ ori tiẹ ko ju mẹrinla lọ.

Ọmọbinrin naa ko gba fun un bo ti daamu ẹ to, nigba to si pẹ to ti n ba a sọ ọ tiyẹn ko gba lo sọ ọ dija mọ ọmọbinrin ọhun lọwọ, niṣe lo dọdẹ ẹ, to si fi lulu ṣe ọmọ naa leṣe, iyẹn lọjọ kẹrinlelogun, oṣu keji, ọdun yii.

Lilu to lu akẹkọọ-binrin ọmọ ileewe Nawair-ud-deen naa pọ to bẹẹ to jẹ ijamba ti ṣe e ninu ara, ṣugbọn kaka kọmọ naa sọ ohun to ṣẹlẹ fawọn obi rẹ, ko tete sọ, niṣe lo n mu inira to n koju mọra.

Nigba ti inira naa pọ, ọmọdebinrin yii ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fawọn obi rẹ, wọn gbe e lọ sọsibitu Jẹnẹra, Ijaye, l’Abẹokuta kan naa fun itọju.

Awọn t’Ijaye tọju ẹ titi, apa wọn ko ka a, ni wọn ba ni ki wọn maa gbe e lọ si FMC, n’Idi-Aba, nibẹ lọmọge naa si pari ẹ si, to dagbere faye.

Ọrọ yii di wahala, wọn mu ọmọkunrin to fẹẹ fagidi yan an lọrẹẹ yii, wọn si ti wa lẹnu ẹ ki kootu too lọ si isinmi iyanṣẹlodi wọn.

Bi wọn ṣe de pada ni wọn gbọ ẹjọ naa, Adajọ si paṣẹ pe ọmọde to daran ipaniyan yii ko gbọdọ fi oju ba ode titi di ọgbọn ọjọ si asiko ta a wa yii, nigba ti DPP to n gba kootu nimọran yoo ti ri nnkan sọ lori ẹjọ to n jẹ.

 

Leave a Reply

%d bloggers like this: