Ọmọ ọdun mejidinlogun dero ile-ẹjọ, ileeṣẹ panapana lo n mu ṣere

Monisọla Saka

Ijọba ipinlẹ Eko ti wọ ọmọkunrin ẹni ọdun mejidinlogun (18) kan, Uzuokwu Solomon, lọ sileẹjọ. Ẹsun ti wọn ka si i lọrun ni pe niṣe lo maa n pe awọn ileeṣẹ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri, ti yoo si tan wọn kuro nileeṣẹ wọn lori nnkan ti ko ṣẹlẹ.

Igbakeji adari eto iroyin atawọn nnkan to ba jẹ mọ ọrọ araalu nileeṣẹ panapana ipinlẹ Eko, Ọlọlade Agboọla, to sọrọ yii di mimọ ninu atẹjade to fi lede lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, sọ pe ọwọ awọn ti tẹ afurasi naa, awọn si ti ṣetan lati wọ ọ lọ si ileẹjọ Majisireeti to wa lagbegbe Ọgba, nipinlẹ Eko, laago mẹsan-an aarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹrin yii.

O ni, “Ni nnkan bii aago mẹfa ku iṣẹju mẹẹẹdọgbọn irọlẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni afurasi pe nọmba pajawiri ileeṣẹ panapana to wa ninu Harmony Estate, Langbasa, Ajah, nipinlẹ Eko, to si jẹ ko ye wọn pe ina n jo lọwọlọwọ nibi kan ninu Estate ọhun. Ni kiakia ni wọn ti ṣa awọn ikọ kan jọ, ti wọn si tun ko ọkọ nla awọn ileeṣẹ panapana lati teṣan wọn to wa ni Lekki Phase 2, ni wọn ba gba ibẹ lọ.

“Wọn debẹ tan ni wọn ri i pe ko si ina kankan to n jo ni adugbo ọhun. Nitori ti ẹni yẹn ti maa n pe iru ipe pajawiri bayii lemọlemọ latẹyinwa, awọn oṣiṣẹ eleto aabo inu Estate ọhun ba wọn ṣewadii ẹni to n daamu awọn oṣiṣẹ ijọba yii, eyi lo si ṣe atọna bi wọn ṣe mu ọmọkunrin torukọ rẹ n jẹ Uzuokwu, to ti jingiri ninu ko maa pe awọn oṣiṣẹ ijọba wọnyi ṣere ọhun”.

Nigba to n fi idunnu rẹ han lori bi ọwọ ṣe pada tẹ afurasi ọdaran naa, Margaret Adeṣẹyẹ, ti i ṣe adari ileeṣẹ panapana ipinlẹ Eko, sọ pe ijọba Eko ko ni faaye gba iru iwa buruku bẹẹ, ati pe ijiya tilẹ wa fun iru ẹṣẹ yii labẹ ofin ileeṣẹ panapana ipinlẹ Eko, ti ọdun 2013.

O tẹsiwaju pe, “Bi ọwọ ṣe tẹ afurasi ọhun, ti wọn yoo si wọ ọ lọ sileẹjọ yii, yoo jẹ ẹkọ fawọn ọmọ orilẹ-ede yii tiru iwa radarada bẹẹ wa lọwọ wọn, to jẹ pe wọn kundun ki wọn maa pe lori nnkan ti ko ṣẹlẹ, ki wọn si tibẹ maa da awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ pajawiri riboribo”.

O ni oun to mu kọrọ naa dun awọn jọjọ ni pe iwa ka maa pe lori ohun ti ko ṣẹlẹ yii ti gogo laarin awọn eeyan lati bii oṣu mẹfa sẹyin nisinyii. Ijọba ko si ni i kawọ bọtan, ko maa woran titi tawọn eeyan yii yoo fi ba ilu jẹ.

 

Leave a Reply