Ọmọ ọdun mẹtala lawọn eleyii ji gbe l’Ado -Ado, ni wọn ba n beere idaji miliọnu naira

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ikọ ajinigbe lawọn gende mẹrin yii, orukọ wọn ni Adeleke Ayọtunde, Adekunle Basit, John Nelson ati Abey Fagbẹmi. Niṣe ni wọn ji ọmọbinrin kan to jẹ ọmọ ọdun mẹtala gbe l’Ado-Odo Ọta, ni wọn ba n beere fun idaji miliọnu owo idasilẹ.

Adejunwọn Ọdunawo ni baba ọmọ ti wọn ji gbe. Oun lo lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa Onipaanu, l’Ọta, pe ọmọ oun, Susan Ọdunowo, di awati lọjọ kẹfa, oṣu karun-un yii, nigba ti iya rẹ ran an niṣẹ ni nnkan bii aago mẹfa aabọ irọlẹ ọjọ naa, bi ko ṣe pada sile mọ niyẹn.

O ni bawọn ṣe n daamu lati ri Susan loun gba ipe kan ti ẹni naa sọ pe boun ba ṣi fẹẹ ri ọmọ oun laaye, afi koun fi ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta ti i ṣe idaji miliọnu nairaa ranṣẹ. Ai jẹ bẹẹ, koun gbagbe nipa riri Susan mọ laye.

Nigba to di ọjọ kẹta iṣẹlẹ yii, awọn ọlọpaa to ṣiṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ri ọkan lara awọn ajinigbe naa mu lagbegbe Sẹlẹ, l’Ọta. Mimu ti wọn mu un lo ṣatọna bi wọn ṣe tun ri awọn meji mi-in mu, ileeṣẹ kan ni wọn ti mu wọn.

Lẹyin ti wọn mu awọn mẹta yii ni aṣiri tu pe yara Adekunle Basit, ẹni kẹrin wọn ni wọn tọju ọmọ ti wọn ji gbe si, bawọn ọlọpaa ṣe lọ sibẹ ti wọn tu ọmọ naa silẹ lai farapa niyẹn, ti wọn si mu Basit naa.

Wọn ti fa Susan le awọn obi rẹ lọwọ, awọn ajinigbe si ti wa lẹka to n tọpinpin iwa ijinigbe.

Awọn ọlọpaa waa kilọ, pe karaalu maa tẹle awọn amọran iṣọraẹni tawọn n fi sita, nitori ijinigbe to gbode kan.

Leave a Reply