Ọmọ ọdun mẹtala ni Julius ki mọlẹ l’Ayetoro, lo ba fipa ba a lo pọ

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Ẹka to n ri si ifipabanilopọ ati ifiyajẹ awọn ọmọde ni ọkunrin yii, Julius Afuapẹ, ẹni ọdun mọkanlelogun, wa bayii nitori ọmọ ọdun mẹtala to fipa ba lo pọ l’Ayetoro, ni ọgbọnjọ, oṣu kẹsan-an, to pari yii.

Ọgbọn buruku ni Julius lo fun ọmọdebinrin naa to fi ba a lo pọ, to si gba ibale rẹ.

Gẹgẹ bi ọmọdebinrin ti wọn forukọ bo laṣiiri naa ṣe ṣalaye, o ni inu ile loun wa lọsan-an ọjọ naa, ni nnkan bii aago kan aabọ ọsan, nigba naa ni Julius tawọn jọ n gbe laduugbo waa kan ilẹkun, to si ni aunti oun (anti ọmọbinrin yii) lo ni koun waa tun jẹnẹretọ ti wọn n lo ṣe.

Aunti ọmọ naa ko si nile lasiko ti Julius wa, iyẹn lo jẹ kọmọbinrin naa ro pe ẹgbọn oun toun n gbe lọdọ ẹ naa lo ni ko waa tun jẹnẹretọ ṣe loootọ, n lo ba jẹ ko wọle.

Ṣugbọn bi Julius ṣe wọle tan, ko fọwọ kan jẹnẹretọ, ọmọbinrin naa lo fipa wọ lọ si yara, to si fipa ba a lo pọ, to gba ibale rẹ. Bo si ṣe ṣere egele naa tan lo sa lọ.

Nigba ti ẹgbọn ọmọ naa de to ba a nipo inira lo beere ohun to ṣẹlẹ, biyẹn si ṣe ṣalaye ni ẹgbọn rẹ mu ẹjọ naa lọ si teṣan ọlọpaa Ayetoro.

DPO teṣan naa, CSP Mobọlaji Jimọh, ni kawọn ọmọọṣẹ rẹ lọọ wa afurasi naa wa, ni wọn ba bẹrẹ si i wa Julius kiri.

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ti i ṣe ọjọ keji, oṣu kẹwaa, ni wọn ri Julius mu nibi to n fara pamọ si, o si jẹwọ pe loootọ loun fipa ba ọmọdebinrin naa lo pọ.

Bi wọn ti mu ọmọbinrin naa lọ sileewosan ti wọn ṣe ayẹwo fun un ni wọn fidi ẹ mulẹ pe ibale abẹ ẹ ti sọnu sọwọ Julius to fipa ṣe kinni fun un.

DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, fidi ẹ mulẹ pe ọkunrin to fipa baayan sun yii ti wa lẹka to n ri si lilo ọmọde nilokulo, gẹgẹ bi CP Edward Ajogun, kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ yii ṣe paṣẹ

Leave a Reply