Ọmọ ọdun mọkandinlogun gbe majele jẹ nitori owo idokoowo ‘Forex’ to padanu

Stephen Ajagbe, Ilorin

Ọmọ ọdun mọkandinlogun kan to jẹ akẹkọọ Fasiti Ilọrin, Gbenga Favour Ọlaoye-Akanbi, la gbọ pe o gbe majele jẹ nitori miliọnu ọgọrun-un mẹta naira toun atawọn ọrẹ rẹ padanu ninu idokoowo ori ẹrọ ayelujara ta a mọ si Forex.

ALAROYE gbọ pe ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, niṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ, ṣugbọn ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni iroyin iku ọdọmọkunrin naa tan kaakiri.

Gẹgẹ bawọn to sun mọ ọn ṣe ṣalaye, ọkunrin kan, Eseka Chuckwutem Gospel (ESG) to n ba wọn ṣe idokoowo Forex naa lo lu akẹkọọ ọhun atawọn ọrẹ rẹ ti wọn jọ ko owo sori owo naa ni jibiti.

Wọn ni Gbenga gba owo lọwọ awọn eeyan kaakiri lati fi dokoowo ọhun ni, to si n ṣeleri fun wọn pe oun yoo da owo wọn pada pẹlu ele ori ẹ.

Ohun ta a gbọ ni pe ọdun yii ni Gbenga atawọn ọrẹ rẹ bẹrẹ idokoowo naa. Gospel ti wọn fi ṣe alarina lo ṣadeede fopin si idokoowo naa lai jẹ kawọn to ni owo mọ si i, o gbe owo wọn wọ itakun sogun-dogoji tawọn oloyinbo n pe ni ‘Ponzi’.

Lẹyin igba diẹ ti ikanni sogun-dogoji ti ESG gbe owo awọn eeyan wọ fori ṣanpọn ni wahala de. Wọn ni gbogbo awọn to ti ri owo gba lori itakun naa ni wọn n wọdii wọn lati da owo naa pada.

Ohun ta a gbọ ni pe nigba tawọn to ya Gbenga lowo duro le e lọrun, tiyẹn ko si mọ ibi to fẹẹ gbe ọrọ naa gba, lo ba ro gbogbo ẹ pọ, o si wo o pe iku ya ju ẹsin lọ, bi wọn lo ṣe gbe majele jẹ niyẹn.

Wọn ni ọkan lara awọn to fi miliọnu marun-un naira sinu idokoowo naa ni oloogbe naa ko ṣalaye foun pe ki i ṣe oun gan-an loun n ṣe idokoowo naa funra oun,  nigba tọrọ bẹrẹ si i yiwọ ninu oṣu kẹfa, ọdun 2020, ni Gbenga n darukọ Eseka Chuckwutem Gospel gẹgẹ bii ọga rẹ.

Nigba tawọn ti Gbenga gba owo lọwọ wọn fi ọlọpaa gbe oun pẹlu Gospel, wọn ni oloogbe naa ṣeleri lati da owo awọn eeyan naa pada lopin oṣu kejila, ọdun 2020, ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe iroyin iku rẹ lawọn eeyan pada gbọ.

Leave a Reply