Ọmọ oojọ lobinrin yii lọọ ji gbe lẹgbẹe iya ẹ lọsibitu

Monisọla Saka

Ọwọ palaba obinrin ẹni ọdun mọkandinlogoji (49), kan ti segi. Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko si ti fi panpẹ ofin gbe e fun ẹsun ọmọ jijigbe. Agbegbe Ojokoro, nipinlẹ Eko, ni wọn ni ọsibitu ti wọn o fẹẹ darukọ rẹ ọhun wa, ọmọ oojọ ni wọn ni obinrin naa n gbiyanju lati ji gbe lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹfa ọdun yii.

Gẹgẹ bi Benjamin Hundeyin, ti i ṣe Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Eko ṣe sọ, o ni awọn eeyan kan ni wọn ta awọn lolobo nipa afurasi yii. Niṣẹ lo wọnu ile iwosan naa wa bii alaisan, to si gbe ọmọ ti wọn ṣẹṣẹ bi naa lọ. Ṣugbọn wọn pada gba obinrin naa mu ni nnkan bii aago mẹfa irọlẹ.

O ni iroyin to tẹ teṣan ọlọpaa naa lọwọ ni pe bii ẹni to waa gba itọju ni obinrin naa ṣe wọ inu ọsibitu ọhun, ko too ji ọmọ naa gbe lọ.

Aklukoro ni, “Iṣẹ abẹ niya ọmọ naa fi bimọ, lasiko to n sun lọwọ lẹyin ti wọn pari iṣẹ abẹ ẹ tan ni afurasi wọle sibi ti iya ọmọ ati ọmọ tuntun naa wa, l ba gbe ọmọkunrin ti wọn ṣẹṣẹ bi naa lọ.

Ọkan ninu awọn alaisan to wa l’ọsibitu ọhun lo ṣakiyesi bi ara afurasi yii ko ṣe balẹ, ati bi irin ẹsẹ rẹ ṣe ya kanmọkanmọ, lọgan lo si ti pe akiyesi awọn alaṣẹ ileewosan naa si i, ko too di pe ọwọ ṣinkun awọn agbofinro tẹ ẹ”.

Nigba ti wọn n fọrọ wa obinrin naa lẹnu wo, afurasi naa jẹwọ pe ipinlẹ Ọyọ loun ti wa, o ni aafaa kan lo ran oun niṣẹ naa, pe ọmọ oojọ ti wọn fẹẹ fi ṣoogun owo ni wọn bẹ oun koun ba wọn wa wa.

Bakan naa ni iwadii tun fidi ẹ mulẹ pe igba akọkọ kọ niyi ti afurasi yii yoo ji ọmọ gbe. O fi kun un pe awọn ti gbe ọmọ pada fun iya ẹ, afurasi naa si ti wa latimọle ọlọpaa. O ni ni kete tawọn ba ti pari iwadii lawọn yoo wọ obinrin yii lọ siwaju adajọ.

Leave a Reply