Florence Babasola, Osogbo
Aarẹ orileede yii tẹle, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, ti fi ọwọ mejeeji sọya pe awọn ọmọ Owu kaakiri orileede yii ki i jale, ati pe eyi ti ẹnikẹni ba gbọ pe ẹni kan jale lara wọn, iru ẹni beẹ gbọdọ jẹ aṣawọ.
Nibi ayẹyẹ ‘Owu National Convention’ ikọkandinlọgbọn iru ẹ to waye laafin Olowu Kuta, nijọba ibilẹ Ayedire, nipinlẹ Ọṣun, ni Oloye Ọbasanjọ ti sọrọ naa.
O ni awokọṣe rere lawọn ọmọ Owu maa n jẹ nibikibi ti wọn ba wa, wọn si maa n da yatọ nidii iṣẹ ti wọn ba yan laayo nitori oloootọ ati ẹni to ṣee fọkan tan ni wọn, ẹni to ba huwa to yatọ, o ni ki wọn beere ibi ti iya rẹ ti gbe e wa.
Ọbasanjọ lo asiko naa lati rọ gbogbo awọn ọmọ Owu ki wọn tubọ maa ran ara wọn lọwọ nibikibi ti wọn ba ti pade ara wọn, o ni erongba ayẹyẹ ti wọn n ṣe naa ni ki awọn eeyan naa le mọ ara wọn si i.
Ninu ọrọ ti Olowu Kuta, Ọba Adekunle Oyelude Makama, o ni Owu jẹ ilẹ iṣọkan ati ilẹ alaafia, o si rọ awọn ọmọ ibẹ lati tẹsiwaju ninu iṣẹ idagbasoke rẹ.
Bakan naa ni ọba naa ṣapejuwe ipenija aabo to wa lọwọlọwọ lorileede yii gẹgẹ bii eyi to wa fungba diẹ, o ni laipẹ, Naijiria yoo bori, alaafia yoo si jọba.