Ọmọ ti Itunu bi ku, lo ba lọọ ji ọmọọlọmọ gbe lati fi rọpo oku ọmọ rẹ n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti tẹ obinrin ẹni ọdun mẹtalelogun (23) kan, Itunu Adepọju, ẹni to ji ọmọ tuntun, ọmọ ọjọ mẹta, gbe n’Ibadan.

Ni nnkan bii ọsẹ meji sẹyin ni Itunu bi abiku ọmọ, ṣugbọn kaka ko gba kadara lori iṣẹlẹ naa, niṣe lo lọọ ji ọmọọlọmọ gbe lati fi i rọpo oku ọmọ rẹ.

Ọmọ ti ọdaju obinrin ọhun ji gbe yii, ile igbẹbi ijọ ẹlẹsin Kirisitẹni kan, iyẹn Yahora Faith Mission House, laduugbo Ita Mẹrin, n’Ibadan, niya ọmọ bimọ rẹ si lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrindilogun (16), oṣu Keje, ọdun yii.

Gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Adewale Ọṣifẹṣọ, ṣe fidi ẹ mulẹ, “ileewosan  Abaẹmu General Hospital, Ọna-Ara, n’Ibadan, nibi ti Itunu ti n gba itọju lọwọ lẹyin to bi abiku ọmọ sileewosan mi-in tan, l’Abilekọ Monsurat Lateef, ẹni ọdun mẹrindinlogoji (36),  ti fẹẹ lọọ gba abẹrẹ ajẹsara fun ọmọ rẹ lo ti pade Itunu.

“Bi Itunu ṣe foju kan Abilekọ Monsura lo ki i kuu oriire pẹlu ọyaya bii ẹni pe wọn ti mọra nibi kan ri tẹlẹ, bo ṣe n ba a gbọmọ lo n ṣaajo rẹ, titi ti iyẹn fi bẹrẹ si i dara de e diẹdiẹ.

“Nibi ti wọn ti jọ n sọrọ ni Itunu ti sọ fun Monsura pe Eko loun n gbe, ṣugbọn oun fẹẹ waa maa gbe Ibadan, nitori naa, oun n wa ile kan niluu naa, niyẹn ba gba lati ba a wale si adugbo wọn.

“Lọjọ yẹn naa ni wọn ti bẹrẹ si i wa ile. Nigba ti wọn yoo fi ri ile, ilẹ ti ṣu, iya ọmọ tuntun yii si gba lati gba obinrin ajeji naa sile lati sun mọju ọjọ keji nitori iyẹn sọ pe laaarọ ọjọ keji lafẹsọna oun yoo fi owo ile ranṣẹ si oun.

“Lọjọ keji, Itunu sọ pe ọkunrin afẹsọna oun ti fi owo naa ranṣẹ, oun fẹẹ sare lọọ gba a lọdọ awọn to n ṣowo olowogbowo (POS), nitosi ile awọn to gba a lalejo. Ọmọ ti Mọnsura ṣẹṣẹ bi si wa lẹyin rẹ nigba naa.

“Obinrin yẹn ti jade tan ki iye iya ọmọ too sọ, pe ko yẹ ki oun jẹ ko pọn ọmọ oun jade bẹẹ. Lọgan lo jade sita lati wa alejo rẹ naa, ṣugbọn ko ri ẹni to jọ ọ.

“Bi wọn ṣe fi iṣẹlẹ yii to wa (awọn ọlọpaa) leti ni CP Adebọwale Williams (ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ) ti gbe awọn ikọ alagbara loriṣiiriṣii dide laarin awọn ọlọpaa lati wa obinrin ajọmọgbe naa kan nibikibi to ba wa.

“Agbegbe Ajah, nipinlẹ Eko, lawọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti ri i mu, ti wọn si doola ọmọọlọmọ to ji gbe kuro lọwọ ẹ.”

Olugbe adugbo Ita-Mẹrin, nitosi ile awọn ọmọ ti wọn ji gbe, Ọlagoke Kẹhinde, ṣalaye f’ALAROYE pe “lasiko ti iya ọmọ n ṣe ounjẹ lọwọ laaarọ ọjọ yẹn lọmọ yẹn bẹrẹ si i sunkun, ti alejo ti wọn gba sile si sọ fun iya ẹ pe ko maa ṣe nnkan to n ṣe lọ, oun yoo ba a gbe ọmọ naa pọn sẹyin.

“Ko pẹ pupọ to pọn ọmọ tan lo sọ fun iya ọmọ pe owo ti afẹsọna oun fẹẹ fi ranṣẹ ti wọle, oun fẹẹ lọọ gba a. Iya ọmọ si fi awọn ọmọ rẹ meji ti i lati tẹle e lọ sibi to n lọ naa.

“Anti Monsura ko sọ fun ọkọ ẹ ti tẹlẹ to fi mu alejo rẹ lọ sile. Ṣadeede niyẹn wọle lalẹ ọjọ naa to ba a, ki Anti too ṣẹṣẹ waa ṣalaye bi ọrọ ṣe jẹ.

“Obinrin yẹn sọ pe oun mọ baba ọmọ daadaa, ati pe ọmọ ọrẹ iya ẹ loun, ṣugbọn baba ọmọ sọ pe ko ma binu, oun ko mọ ọn ni.

Lasiko ti wọn lọọ gbowo yẹn ni baba ọmọ pe iyawo ẹ, o ni oun ti pe iya oun nipa alejo awọn. Lẹyin ti oun si juwe rẹ fun iya oun, iyẹn sọ pe oun ko mọ ọn rara. Asiko yii l’Anti sare jade, to si ba awọn ọmọ rẹ nikan nibi POS ti wọn ti n gbowo. O beere alejo rẹ to pọnmọ sẹyin, awọn ọmọ ni o ti lọ sibomi-in lati gbowo nigba ti ko rowo ọhun gba nibi, oun lo ni ki awọn duro de oun ki oun fi yara lọọ gbowo naa nibomi-in”.

“Bi Anti ṣe wa ọrẹ wọn apapandodo ti niyẹn o”.

Ni bayii ti ọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ obinrin ẹni ọdun mẹtalelogun (23) to fi ọgbọn arekereke ji ọmọọlọmọ gbe naa, CP Willams ti ṣeleri lati pe kootu  lo n lọ ni kete ti wọn ba pari gbogbo iwadii wọn tan lori iṣẹlẹ yii.

Leave a Reply