Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Awọn agba bọ, wọn ni ‘ọrọ to n pa oloko lẹkun ni aparo fi n ṣẹrin-in-rin’. Bẹẹ lọrọ ri nile-ẹjọ kọkọ-kọkọ kan to wa lagbegbe Akérébíata, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹta, oṣu Keje, ọdun 2024 yii, nigba tiyawo ile kan, Abilekọ Arọgbọnlo Oluwarẹmilẹkun, n rojọ ohun toju rẹ ri lọdọ ọkọ to bimọ mẹta fun.
Iyaale ile yii n bẹ adajọ ile-ẹjọ naa, Onidaajọ Sakariyau Abdulrasak, pe ko ba oun tu igbeyawo ọlọdun gbọọrọ to wa laarin oun ati ọkọ oun, Yusuf Dare, ka, ki adajọ si faaye gba oun lati maa ṣetọju awọn ọmọ awọn lọ. Bẹẹ lo ni ki wọn paṣẹ fun baale ile naa lati maa san owo ounjẹ awọn ọmọ naa atawọn ohun miiran ti wọn ba nilo nigba gbogbo.
Nigba to n ṣalaye idi to fi fẹẹ kọ ọkọ rẹ silẹ, iyaale ile yii sọ pe Yusuf ki i ṣe ojuṣe rẹ ninu ile mọ, ati pe oun ko le fẹ ẹ mọ laelae nitori pe ṣe lo pero le oun lori ninu ọja, to si n pariwo aṣẹwo le oun lori, ara oun si ti kọ gbogbo iya toun n jẹ lọdọ baba ọmọ oun bayii.
‘‘Yato si pe ọkọ mi pero le mi lori laarin ọja, o tun fẹẹ pa mi. Eyi to si buru ju ninu iwa rẹ ni pe awọn ọmọọṣẹ mi lo n pe, o tun n dẹnu ifẹ kọ akọbi ọmọ mi obinrin ti mo kọkọ bi fun ọkọ aarọ mi.
‘Oluwa mi, ti mo ba ni ki n tẹsiwaju pẹlu ọkunrin yii, yoo pa mi ni, mo gbiyanju agbara mi boya yoo yipada, ṣugbọn pabo lo ja si.
Ninu ọrọ ti olujẹjọ, Ọgbẹni Yusuf Dare, ti i ṣe ọkọ Arọgbọnlo, o sọ fun ile-ẹjọ pe irọ ni iyawo oun pa, oun ko kọ’nu ifẹ si ọmọ rẹ, ati pe iyawo oun n ṣagbere lo jẹ ki oun maa ba a ja, nibi tọrọ naa si buru de, o gbe ọkunrin miiran wa sile.
Ni igunlẹ ọrọ rẹ, o ni oun paapaa ko nifẹẹ obinrin naa mọ, ati pe ẹgbẹrun marun-un Naira ni oun lagbara lati maa san gẹgẹ bii owo ounjẹ awọn ọmọ mẹtẹẹta.
Adajọ Abdulrasak, paṣẹ ki olujẹjọ maa san ẹgbẹrun lọna ogun Naira (20,000) loṣooṣu fun iya awọn ọmọ rẹ gẹgẹ bii owo ounjẹ, ko si maa san owo ileewe ọkan ninu awọn ọmọ mẹtẹẹta gẹgẹ bi olupẹjọ ṣe ni oun yoo maa san owo ileewe ọmọ meji, ki baba wọn maa san owo ẹyọ kan. O fi kun un pe ki Yusuf Dare maa san ẹgbẹrun lọna mọkanla Naira (11000) gẹgẹ bii owo ileewe ni taamu kọọkan.
Lẹyin eyi lo sun igbẹjo si ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Keje, ọdun 2024 yii, gẹgẹ bii ọjọ ti wọn yoo waa gba idajọ ni kootu.