Ọmọ tiwa nilẹ Hausa ni Kayọde Fayẹmi- Sultan lo sọ bẹẹ

Aderohunmu Kazeem

Ọba ilu Sokoto, Sa’ad Abubakar, ti sọ pe ọmọ awọn daadaa ni Gomina ipinlẹ Ekiti, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi, ati pe baba nla awọn, Sir Ahmadu Bello, paapaa lo gba a tọ bii ọmọ.

Ki i ṣe ọba alaye yii nikan lo sọrọ ọhun o, bi Nasir El-Rufai, gomina ipinlẹ Kaduna, naa ti ṣe gba ẹrọ amohun-dun-gbẹmu, niṣe loun naa sọ pe ko si irọ ninu ohun ti Ọba Sokoto, sọ, ati pe idi ti awọn tawọn jẹ ọmọ Hausa, ṣe gba ọkunrin ọmọ Ekiti, yii ni ọmọ awọn, gbogbo eeyan naa ni yoo ri aṣiri ọrọ ọhun laipẹ jọjọ.

Nibi etọ kan ti awọn ọmọ Hausa pejọ si bamu ni ọrọ yii ti jẹ jade, ayẹyẹ aadọta ọdun ti Arewa House ti wa, gbongan nla ti wọn maa n ko gbogbo ohun to jẹ mọ itan ati ohun iṣenbaye awọn Hausa si ni.

Lasiko ti Ọba naa n ki awọn eeyan kaabọ lo sọrọ ọhun. Nigba ti Nasiru, gomina Kaduna, naa yoo si sọrọ, niṣe lo kin ọba ọhun lẹyin, to si fidi ẹ mulẹ pe awọn ti awọn jẹ ọmọ Hausa ki i ṣadeede ṣe nnkan ti ko ba ni idi pataki.

Lọjọ naa, Dokita Kayọde Fayẹmi ni alejo pataki to ba awọn eeyan sọrọ nibẹ. Gbogbo awọn eeyan to si gbọ bi awọn Hausa ṣe sọ ọkunrin oloṣelu ọmọ Ekiti yii dọmọ wọn lojiji ni wọn n sọ pe ọrọ naa yoo too ye kaluku, gẹgẹ bi Nasiru El-Rudfai ṣe sọ, paapaa bi eto oṣelu ọdun 2023 ṣe n sare kan ilẹkun gbọngbọn.

Leave a Reply