Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Alakooso ẹgbẹ to n ṣe itaniji kaakiri lori didu ipo aarẹ orileede Naijiria fun gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ, Aṣiwaju Bọla Hammed Tinubu, niha Iwọ-Oorun (South West Agenda for Tinubu), Sẹnetọ Dayọ Adeyẹye, ti sọ pe ọmọ Yoruba atata kan ṣoṣo to kaato lati gba ijọba lọwọ Aarẹ Buhari ni Tinubu.
Lasiko ti wọn n ṣefilọlẹ SWAGA ni ẹkun idibo Irewọle, ninu eyi tijọba ibilẹ Ayedaade, Irewọle ati Iṣọkan wa, ni Adeyẹye ti sọrọ naa pe ogunlọgọ awọn ọba ilẹ Yoruba ni wọn ti fi ọwọ si erongba naa.
O ni, “Gbogbo ọba ilẹ Yoruba ni wọn ti fọwọ si i, awọn ọba ti wọn to ọọdunrun ni wọn ti fọwọ si i, lati ori Ọọni ti Ifẹ, Alaafin ti Ọyọ, Alake ilẹ Ẹgba ati bẹẹ bẹẹ lọ.
“Aṣiwaju Bọla Hameed Tinubu ni gbogbo Yoruba gbe kalẹ lati di aarẹ Naijiria, awọn iyalọja fọwọ si i, awọn ọdọ fọwọ si i, gbogbo eeyan ni wọn fọwọ si i.
“Nnkan rere ni Aṣiwaju n ko bọ fun Naijiria, nnkan rere lo n ko bọ fun ipinlẹ Ọṣun, oun lo mu ki oṣelu rọrun lorileede yii.”
Adeyẹye waa rọ gbogbo awọn eeyan ẹkun idibo naa lati maa lọ lati ojule de ojule lati ṣetaniji ati ipolongo fun awọn eeyan nipa ohun rere ti yoo ba iran Yoruba ti wọn ba fi ibo gbe Tinubu de ipo aarẹ lọdun un 2023.
Ninu orọ tirẹ, alakoso SWAGA nipinlẹ Ọṣun, Ọnarebu Ayọ Omidiran, ṣalaye pe ohun kan ṣoṣo ti yoo jẹ atọna fun ijawe olubori Tinubu gẹgẹ bii aarẹ ni ki awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun fi ibo wọn gbe Gomina Oyetọla wọle pada.
Omidiran ni, “Ibo gomina l’Ọṣun lo maa ṣatọkun ibo aarẹ, ki ibo aarẹ ma baa wọ, a ni lati mojuto ibo gomina, ka gbaruku ti Gomina Oyetọla, ki ileri Oluwa baa le ṣẹ lẹẹkan si i”
Ijọba ibilẹ mẹtẹẹta ti awọn eeyan naa lọ ni awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ti tu yaaya jade si wọn, ti gbogbo awọn oloye ẹgbẹ si n jẹjẹẹ atilẹyin wọn fun erongba Bọla Hameed Tinubu fun ọdun 2023.