Ọmọ Yoruba atata ni ọ, Ọọni atawọn gomina kan saara si Yẹmi Ọṣinbajo

Jọkẹ Amọri

Ọọni Ileefẹ, Ọba Ẹnitan Ogunwusi, atawọn gomina ilẹ Yoruba kan ti kan saara si Igbakeji Aarẹ ilẹ wa, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, ẹni ti wọn pe ni ọmọluabi ati alatilẹyin awọn ọmọ Yoruba nileejọba.

Ọrọ yii waye lọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, lasiko ti ileewe giga Yunifasiti Ifẹ n ṣe ajọdun ọgọta ọdun ti wọn ti da ileewe naa silẹ, ti wọn si tun n ṣayẹyẹ ikẹkọọ-gboye fawọn ọmọwe. Bẹẹ ni wọn tun fi oye ọmọwe da awọn eekan eekan Yoruba kan lọla, ninu eyi ti Ọọni ati Oloye Micheal Ade-Ojo wa.

Nigba ti Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, to jẹ oludanilẹkọọ eto ikẹkọọ-gboye naa n sọrọ, o ni ‘‘Ọmọluabi eeyan ni Igbakeji Aarẹ, mo le jẹrii si eleyii.’’ Akeredolu ni Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo gẹgẹ bii alaga Igbimọ to n ri si ọrọ-aje apapọ ilẹ wa n ran awọn ipinlẹ lọwọ. O ni ọpọ igba lo ti ja fun awọn gomina ki wọn le baa rowo na ni ipinlẹ wọn. ‘A dupẹ lọwọ yin o’. Akeredolu lo pari ọrọ rẹ bẹẹ.

Bakan naa ni Ọọni Ileefẹ, Ẹnitan Ogunwusi ninu ọrọ tiẹ ṣapejuwe Ọṣinbajo gẹgẹ bii ọmọ Yoruba atata ti ko ṣee fọwọ rọ sẹyin. Ogunwusi ni, ‘‘Iwuri ni Ọṣinbajo jẹ fun wa ninu gbogbo ohun to n ṣe ninu ero ati iṣe.’’

Lẹyin ti Ọọni sọrọ yii lo rọ gbogbo awọn to wa lori  ijokoo, ninu eyi ti awọn eeyan nla nla nilẹ wa, ọba, awọn ọba, awọn ọmọwe atawọn akẹkọọ-jade to wa nibẹ lati lu Igbakeji Aarẹ ilẹ wa lọgọ ẹnu. Nise ni gbọngan ibi ti eto naa ti waye mi titi nigba ti ogunlọgọ awọn eeyan to wa nibẹ pariwo lati bu ola fun Ọṣinbajo.

Bakan naa ni Etsu Nupe, Alaaji Dokita Yahaya Abubakar gboriyin fun Ọṣinbajo, ẹni to ṣapejuwe gẹgẹ bii ẹni to n jẹ olugbeja fun ilu Nupe.

Ọpọ awọn eeyan nla nla lo peju sibi eto naa ti Ọṣinbajo ti waa ṣoju Aarẹ Muhammadu Buhari.

Leave a Reply