Ọmọbinrin ti Ṣeun fẹẹ fẹ loun atọrẹ ẹ fipa ba lo pọ l’Abẹokuta

Gbenga Amos, Abẹokuta

Erokero to wọnu awọn gende meji yii, Ṣeun Orokunle, ẹni ọdun mejidinlogoji, ati ọrẹ rẹ, Sọdiq Sarumi, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, tawọn mejeeji fi ki ọmọbinrin ẹni ọdun mejilelogun mọlẹ ni baluwẹ tiyẹn ti n wẹ, ti wọn lu u lalubami, ti wọn si bẹrẹ si i fipa ba a sun, afaimọ niwa buruku naa ko ni i sọ wọn dero atimọle laipẹ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, to fi iṣẹlẹ yii to ALAROYE leti ninu atẹjade kan ṣọwọ sọ pe ọmọbinrin ti wọn fipa ba lo pọ naa lo waa fẹjọ awọn afurasi ọdaran mejeeji sun ni tọlọpaa, laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹta yii.

Ọdọbinrin naa sọ pe ọrẹkunrin oun ni Ṣeun, awọn si ti jọ wa tipẹ, tawọn n fẹra. O loun lọ sile bọifurẹndi oun yii gẹgẹ boun ṣe maa n lọ, nigba toun si debẹ, oun bọ si baluwẹ lati bomi sara.

Ṣugbọn lojiji ni Sọdiq wọle waa ba oun, lo ba gba oun mu latẹyin nibi toun ti n wẹ, o loun kọkọ ro pe afẹsọna oun ni, afi bo ṣe di ọrẹ rẹ, lo ba wọ oun jade.

Kaka ki Ṣeun si gbeja oun, niṣe lawọn mejeeji bẹrẹ si i lu oun, lẹyin eyi ni wọn fipa ba oun laṣepọ, o ni niṣe lawọn mejeeji n to tọọnu lori oun, bi ẹni kan ṣe n bọọlẹ lẹni keji n goke.

Ọmọbinrin naa ni nigba tawọn mejeeji ti tẹ ifẹ ọkan wọn lọrun daadaa tan, niṣe lọrẹkunrin oun ko aṣọ oun, lo ba ki i bọ omi to wa ninu bọkẹẹti kan nile naa, o ni tori koun ma baa tete raaye kuro nibẹ ni wọn ṣe ṣe bẹẹ.

Wọn lọmọbinrin naa tun ṣalaye pe ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun lawọn mejeeji, wọn si ti halẹ mọ oun pe iku loun maa fi ṣefa jẹ ti awo iṣẹlẹ naa ba fi lu sita pẹnrẹn.

Loju-ẹsẹ ti DSP Badmus Ọpẹyẹmi to wa lẹka tawọn araalu ti n fẹjọ sun ṣe gbọ aroye ọmọbinrin naa ni wọn ni kawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ wa awọn afurasi naa kan, ṣugbọn wọn ti sa kuro nile, agbegbe Arẹgbẹ, l’Abẹokuta, lọwọ ti pada tẹ wọn, ti wọn si mu wọn.

Nigba ti wọn de tọlọpaa, wọn jẹwọ pe loootọ lawọn to tọọnu lori ọmọọlọmọ, wọn lawọn fipa ba a sun.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankọle, ti gbọ sọrọ yii, o si ti paṣẹ pe ki wọn taari Ṣeun ati Sọdiq si ẹka ọtẹlumuyẹ ti wọn maa n bojuto iru iwa palapala bii eyi. Ibẹ ni wọn ti n ṣalaye ara wọn lọwọ.

Leave a Reply