Awọn ọlọpaa ti mu Ẹniọla Ayọdele ati Kayọde Babaṣọla ni Dọpẹmu, Ageege, nitori pe wọn gun Muhammed Ọbadimeji lọbẹ pa. Ki Ọlọrun ma jẹ ka rin arinfẹsẹsun ni: ọrọ ti ko kan ọmọkunrin yii ni wọn tori ẹ pa a. Ẹniọla ati Kayọde lo n ja nitori ọmọge Barakat, ija ni Muhammed fẹẹ la, ni Ẹniọla ba ṣeeṣi fi ọbẹ to fẹẹ fi gun Kayọde gun Muhammed, niyẹn ba ṣe bẹẹ ku o.
Ọrọ Barakat Wasiu ti n da ija silẹ laarin Kayọde ati Ẹniọla to ọjọ mẹta kan, ọmọ ti ko si ti i pe ogun ọdun ni Barakat yii, ṣugọn awọn mejeeji yii ni wọn n le e kiri. Lọsẹ to kọja ni ija naa kuku doju ẹ, to si di pe awọn mejeeji lọ mọ ara wọn ni gbangba ode. Ki ọrọ naa ma di ohun ti yoo le ju bẹẹ lọ ni Muhammed ṣe sun mọ wọn to si n la wọn. Ṣugbọn wọn ni bi Ẹniọla ti fẹẹ fi ọbẹ gun alatako rẹ, iyẹn Kayọde, ti iyẹn yẹ kinni ọhun, kongẹ aya Muhammed ni ọbẹ naa ṣe, lo ba dà á dé e.
Muhammed ṣubu lulẹ, wọn sare gbe e de ọsibitu Jẹnẹra n’Ikẹja, ṣugbọn itọju naa ko ti i debi kan to fi dagbere faye. N lawọn ọlopaa ba gba Kayọde ati Eniọla mu, ti wọn si mu Barakat naa mọ wọn. Wọn ti gbe wọn lọ si teṣan Panti ni Yaba, lọdọ awọn ọlọpaa ti wọn n gbọ ẹjọ awọn ogbologboo ọdaran.