Ọmọkunrin kan ṣoṣo ti Ọba Elegushi bi ku lojiji

Ọrẹoluwa Adedeji

Asiko yii ki i ṣe eyi to daa fun ọkan ninu awọn ọba ipinlẹ Eko, Ọba Saheed Elegushi ti ilẹ Ikate, pẹlu bi ọba alaye naa ṣe padanu ọmọkunrin kan ṣoṣo to bi laipẹ yii.

ALAROYE gbọ pe ọmọ to ku yii ko ti i ju ọmọ ọdun kan ataabọ lọ, ṣugbọn oun lo da bii arole kabiyesi nitori pe akọbi rẹ lọkunrin ni.

Iyawo keji to jẹ ọmọ ilẹ Hausa, Hadiza Tanko- Elegushi, ti kabiyesi fẹ lo bi ọmọ naa fun un lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun  2020.

Gbogbo awọn ti wọn gbọ nipa iṣẹlẹ naa ni wọn ti n ki kabiyesi ku irọju ati atẹmọra, ti wọn si n gbadura pe ki Ọlọrun ṣe eyi ti yoo mọ ọwọ fun ọba alaye naa.

Ọjọ kẹta, oṣu Karun-un, ọdun 2019, ni Ọba Elegushi gbe obinrin naa niyawo.

Leave a Reply