Ọmọọdun mẹtadinlogun gun ọga ẹ pa, ibi to ti fẹẹ ta mọto ẹ to ji lọwọ ti tẹ ẹ ni Benin

Faith Adebọla
Wọn lọjọ ori ọmọkunrin yii ko ju mẹtadinlogun lọ, ṣugbọn iwa buruku to hu ṣi n ya ọpọ eeyan lẹnu pe bawo lọmọde ṣe le gbọn ọgbọn buruku bẹẹ, niṣe ni Chukwuebuka Nwode yọ ọbẹ si ọga ẹ lojiji, o gun un pa, lo ba ki mọto ọga naa mọlẹ, o gbe e lọ sibi to ti fẹẹ ta a, ibẹ si ni wọn ka a mọ.
Ilu Benin, nipinlẹ Edo, niṣẹlẹ yii ti waye laarin ọsẹ to kọja yii. Ile kan naa ni afurasi ọdaran yii ati ọga rẹ, Ọgbẹni Peter Omoberhie, n gbe. Iṣẹ omi inu ọra, iyẹn piọ wọta ni wọn n ṣe.
Bi Nwode ṣe fẹnu ara ẹ sọ lagọọ ọlọpaa, o ni oun ko mọ nnkan to rọ lu oun toun fi huwa buruku naa.
“Mi o mọ nnkan to ṣe mi ti mo fi pa a. Ọdọ mama mi nipinlẹ Ondo ni mo n gbe latigba ti wọn ti bi mi. Ọdun to kọja yii ti mo di ọmọọdun mẹrindinlogun ni mo wa si Benin, mo kọkọ lọọ ṣiṣẹ nibi ti wọn ti n ṣe burẹdi, mo sare lọọ yọju si mama mi, ṣugbọn nigba ti ma a fi pada de, wọn ni iṣẹ ti tan.
Eyi lo mu ki n waṣẹ lọ sibi ti wọn ti n ṣe piọ wọta yii. Lẹyin ti mo ti ṣiṣẹ fọjọ diẹ, mo kan ronu pe ki n pa ọga mi, ki n si ji mọto ẹ gbe. Bi mo ṣe yọ kẹlẹ lọọ ba wọn nibi ti wọn ti n wo tẹlifiṣan loru niyẹn, ọbẹ ti mo mu ni kiṣinni wa ni mo fi gun un pa.
Nigba tilẹ mọ, tẹnikẹni o ti i mọ nnkan kan, mo wa ẹni to mọ mọto i wa lọ sagbegbe Ring Road, ni Benin, tori emi o mọ ọn wa. Ẹni kan tẹle mi, oun lo wa mọto naa jade ninu ọgba, a si jọ gbe e lọ si ọja ti wọn ti n ta ẹya ara ọkọ niluu Uwelu, lati ta a ni gbanjo.
Ibẹ lawọn fijilante kan ti fura si wa, ti wọn si mu wa, ni wọn ba fa wa le ọlọpaa lọwọ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Edo ni afurasi ọdaran yii ati awọn meji ti wọn mọ nipa iṣẹlẹ yii lawọn ti mu sahaamọ, wọn si ti wa lẹka to n tọpinpin iwa ọdaran bii eyi.

Leave a Reply