Ọmọkunrin yii gun lanlọọdu ẹ pa nitori obinrin

Njẹ ẹyin gbọ nipa ọmọkunrin ẹni ọdun mọkanlelogun kan to gun lanlọọdu ẹ pa lọsẹ to kọja yii nipinlẹ Anambra? Bẹẹ, amọran lasan ni baba onile rẹ yii gba a, o ni ko yee ko obinrin oriṣiiriṣii wale. Ohun to bi ayalegbe torukọ ẹ n jẹ Onyemachi Mmaju ninu niyẹn to fi gun lanlọọdu ẹ torukọ iyẹn n jẹ Umeadi Oyiboka, pa.

Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Anambra, SP Haruna Mohammed, ṣalaye pe ọkunrin to doloogbe yii jogun ile naa ni, oun kọ lo kọ ọ. O ni ṣugbọn oun ni alaṣẹ ile ọhun, bo tilẹ jẹ pe ko ju ẹni ọdun marundinlogoji (35) lọ.

O lo pẹ ti ayalegbe yii ti maa n gbe awọn obinrin oriṣiiriṣii wale, to jẹ bo ṣe n gbe dudu lo n gbe pupa, o si ti fẹrẹ sọ yara to gba naa di otẹẹli, ko mọ ju obinrin lọ.

Ohun to n ṣe yii ni lanlọọdu ẹ maa n ba a wi fun, ti yoo ni ko ma para ẹ, to ba fẹẹ fẹyawo ko mu ọkan ninu awọn obinrin yii, iyẹn daa ju ko maa gbe dudu, gbe pupa, kiri lọ.

Amọran yii ki i tẹ Onyemachi lọrun, wọn ni niṣe lo maa n bu lanlọọdu rẹ, ti yoo ni ko jẹ koun jaye ori oun, ko fi tiẹ ṣe tiẹ.

Lọjọ kẹfa, oṣu kẹwaa yii, ṣa, amọran ti lanlọọdu fun tẹnanti ẹ yii gbodi lara ayalegbe rẹ, inu bi Onyemachi, lo ba kọju ija si baba onile rẹ, o si fi ọbẹ gun un lẹyin.

Wọn sare gbe lanlọọdu lọ si ‘Iyi Enu Mission Hospital’, ṣugbọn iku ti pa oju ọkunrin naa de, awọn dokita ko ri i ji saye rara.

Kootu ni yoo gba ayalegbe to paayan yii lalejo laipẹ, ibẹ ni yoo ti ṣalaye ohun to ko si i lori to fi gun lanlọọdu ẹ pa.

Leave a Reply