Ọmọọṣẹ Adedoyin t’adajọ ju sẹwọn wo lulẹ ni kootu

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Adeṣọla Adedeji, akọwe otẹẹli Hilton niluu Ileefẹ, ti Timothy Adegoke ba nigba to debẹ lọjọ karun-un oṣu Kọkanla, ọdun 2021, ni ile-ẹjọ ti ju sẹwọn ọdun meji bayii.

Gẹgẹ bi Onidaajọ Bọla Adepele Ojo ṣe wi, ẹsun yiyi ẹri to fi han pe Adegoke de si otẹẹli naa lo wa lọrun Adeṣọla, ṣugbọn fun ẹbẹ ti agbẹjọro rẹ ati agbẹjọro olupẹjọ bẹ ile-ẹjọ lori ọrọ rẹ lo ṣe ju u sẹwọn ọdun meji.

Adepele Ojo fi kun idajọ naa pe ki Adeṣọla bẹrẹ kika asiko ẹwọn rẹ lati ọjọ to ti wa lakolo awọn ọlọpaa ninu oṣu Kọkanla, ọdun 2021.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni wọn dajọ iku fun Dokita Adedoyin atawọn oṣiṣẹ rẹ meji lori ẹsun pe wọn lọwọ ninu iku Timothy Adegoke to jẹ akẹkọọ fasiti Ifẹ to ku si otẹẹli Hilton lọdun 2021.

 

Leave a Reply