Ọmọọdọ atọmọ ti Kinsley bi ninu ara ẹ lo n ba laṣepọ ni Festac

Faith Adebọla, Eko

Agbọ-ṣe-haa lọrọ ọhun, afi bii ere ori itage, ṣugbọn iṣẹlẹ to waye gidi ni, baale ile ẹni ọdun marundinlogoji kan, Kingsley Achugbu to n gbe lagbegbe Festac, nijọba ibilẹ Amuwo-Ọdọfin, nipinlẹ Eko, lawọn ọlọpaa ti fi pampẹ ofin gbe bayii. Wọn ni iṣekuṣe tiẹ tun legba kan,nitori  bo ṣe n ko ibasun ya ọmọọdọ wọn, lo tun ki ọmọ bibi inu ẹ ti ko ju ọmọ ọdun meji mọlẹ, o si ṣọmọ ọhun yankanyankan.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu, lo ṣalaye pe awọn agbofinro to wa ni teṣan ọlọpaa Festac loun paṣẹ fun pe ki wọn lọọ fi pampẹ ofin gbe afurasi ọdaran yii, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu yii.

Wọn ni Abilekọ Justina Nelson to jẹ aṣoju ajọ ajafẹtọọ awọn ọmọ ti wọn n ṣe niṣekuṣe to jẹ taladaani (Children and Vulnerable Persons), ati ọmọọdọ tọkunrin naa n ba laṣepọ, ti wọn o fẹẹ darukọ ẹ, ni wọn jọ lọọ fẹjọ baba oniṣekuṣe yii sun ni teṣan ọlọpaa laaarọ ọjọ naa.

Ni teṣan, wọn lọmọọdọ yii ṣalaye bi Kingsley ṣe n ki oun mọlẹ nigbakugba ti iyawo rẹ ko ba si nile, ọmọbinrin naa lọkunrin yii lo gba ibale oun.

O ni pẹlu ibẹru loun fi n gbe ile wọn, tori afurasi ọdaran yii ti ni oun maa fimu oun danrin ni toun ba fi le jẹ ki aṣiiri naa tu sita.

Abilekọ Justina tun ṣalaye pe wọn ka afurasi ọdaran ọhun mọ ibi to ti n ṣe ọmọ ikoko, ọmọ ọdun meji, tiyawo ẹ n tọ lọwọ, niṣekuṣe, ẹkun asun-un-da ọmọọwọ naa lo taṣiiri kọlọransi ẹda yii, ti ajọ awọn fi gbọ si i, ki wọn too mẹjọ wa si tọlọpaa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko, Olumuyiwa Adejọbi, sọ pe afurasi ọdaran naa ti wa lakolo awọn, ni ẹka ọtẹlẹmuyẹ to n ri si iwa ọdaran abẹle ni Panti, Yaba, ibẹ lo ti n ṣalaye ohun to ri lọbẹ to fi waro ọwọ.

Bakan naa ni wọn ti gbe ikoko ti baba ẹ fẹẹ baye ẹ jẹ yii lọ sọsibitu fun ayẹwo ati itọju, ọmọọdọ naa si ti lọ fun itọju pẹlu.

Kọmiṣanna Odumosu ni ileeṣẹ ọlọpaa Eko ko ni i dọwọ bo ẹnikẹni ti wọn ba fẹsun iru iwa ibajẹ bii eyi kan nipinlẹ Eko, o lawọn maa jẹ konitọhun jẹ iyan ẹ niṣu gidi ni, to ba fi le jẹbi nile-ẹjọ.

Leave a Reply