Ọmọọdọ ji ọmọ ọga rẹ gbe sa lọ l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Titi di ba a ṣe ṣe n sọ yii ni wọn ṣi n wa ọmọ ọdọ kan to ji ọmọ ọga rẹ gbe sa lọ lọjọ keji ọdun tuntun niluu Ondo.

ALAROYE fidi rẹ mulẹ ninu alaye ti iya ọmọ fun ra rẹ, Abilekọ Babatunde Stella Jimọh, ṣe ni pe ko ti i ju bii ọsẹ mẹta pere ti oun ati ọmọbinrin to n ṣiṣẹ ajọmọgbe ọhun mọ ara wọn.

O ni ọkọ oun, Ọgbẹni Wasiu Mamukuyọmi Jimọh, lo deedee gbe ọmọbìnrin naa lẹyin waa ba oun ni ṣọọbu oun to wa lagbegbe Oke-Bọla, Ayeyemi, niluu Ondo, ni nnkan bii ọsẹ mẹta sẹyin pe o fẹẹ waa kọsẹ aṣọ riran (telọ) lọdọ oun.

Alaye ti ọkunrin yii ṣe fun iyawo rẹ ni pe, iyawo ọrẹ oun ni, ati pe ilu Ọrẹ, nijọba ibilẹ Odigbo, lọkọ rẹ ti n ṣiṣẹ.

Abilekọ yii ni Bọsẹ lo pe orukọ ara rẹ foun nigba to kọkọ de, sugbọn lẹyin-o-rẹyin loun tun gbọ pe Adeniyi Temitope Faith lo n pe ara rẹ ninu ile to n gbe.

A gbọ pe baba ọmọ to sọnu yii ti kọkọ gbe ọmọbinrin naa wa sile wọn ti wọn n gbe lagbegbe Elewuro, Ade Super, lọjọ Keresi, ti wọn si jọ ṣere titi tilẹ ọjọ naa fi ṣu ko too pada lọ.

Bi ilẹ̀ ọjọ keji ọdun tuntun ṣe n mọ lobinrin yii tun pada waa ba ọga rẹ ni ṣọọbu, loju rẹ ni wọn ṣe wẹ ọmọ oṣu mẹta ọhun tan, ti wọn si tẹ ẹ silẹ lori ẹni ko le raaye sun daadaa.

Nigba to di nnkan bii aago mẹrin irọlẹ ni wọn lo gbe ọmọdebinrin ọhun pọn, to si bẹ ọga rẹ pe ko fun oun ni ẹrọ ipọwo rẹ koun le lọọ gba ẹgbẹrun mẹta naira ti ẹnikan fi ranṣẹ soun ni ṣọọbu awọn oni POS to wa lẹgbẹẹ ibẹ.

Lẹyin bii wakati kan to ti lọ, ti iya ọmọ ko ri i ko pada wa lo bẹrẹ si i wa a kiri adugbo.

Nigba ti wọn yẹ foonu to fi sori tabili kan ninu ṣọọbu wo ni wọn ṣakiyesi pe o ti yọ siimu mejeeji to wa ninu rẹ lọ, bẹẹ lo tun pa gbogbo awọn nnkan to wa ninu foonu ọhun rẹ patapata.

Abilekọ Stella ni oun nigbagbọ pe ọkọ oun mọ nipa iṣẹlẹ naa daadaa.

O ni ohun to kọkọ fu oun lara si ọkunrin ọmọ bibi ilu Ondo ọhun ni pe o to bii wakati meji ti oun ti n pe e lẹyin ti wọn gbe ọmọ lọ, sugbọn ti ko gbe e.

O ni ṣe lo tun n ba oun ja nigba to de ti oun ṣalaye ohun to sẹlẹ fun un, bẹẹ ni ko fihan ninu iwa rẹ lọjọ naa pe o bikita lori ọmọ awọn to sọnu.

Lọna kejì, obinrin to n ṣiṣẹ telọ naa ni ọkọ oun pada jẹwọ ni tesan ọlọpaa Ẹnuọwa ti wọn gbe e lọ pe ọrẹbinrin oun ni Bọsẹ to ji ọmọ oun gbe.

O ni funra rẹ lo tun lọọ gba ile to n gbe laduugbo Ewejẹ, lagbegbe Iluyẹmi, Yaba, niluu Ondo fun un.

O ni gbogbo ibi ti awọn n wa ọmọ naa lọ ni wọn ti n sọ fawọn pe ki awon lọọ mu ọkọ oun daadaa, wọn lo mọ nipa bi ọmọ rẹ ṣe sọnu, ati pe oogun owo lo fẹẹ fi i ṣe.

Abilekọ Stella rọ gbogbo ọmọ Naijiria ki wọn ba oun bẹ baba ọmọ oun ko le tete wa ale rẹ to ji oun lọmọ gbe jade nibi to ba gbe e pamọ si.

Atimọle awọn ọlọpaa tesan Ẹnuọwa ti ọkunrin naa wa ko fun wa laaye lati ri i ba sọrọ lasiko ta a ko n iroyin yii jọ lọwọ.

Leave a Reply