Gbenga Amos, Abẹokuta
Ọjọ-ori ọmọkunrin ti wọn porukọ ẹ ni Abiọdun Elegbede yii ko ti i pe ogun o, ọmọọdun mọkandinlogun pere ni, amọ o ti gbo’wọ ninu iwa fifoganna ati ole, ṣọọṣi kan ati ile meji lo fọ loru mọju Ọjọruu, Tọsidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kin-in-ni yii, n’Ilaro, ipinlẹ Ogun, tọwọ awọn ẹṣọ alaabo So-Safe fi tẹ ẹ.
Ọga agba ajọ So-Safe, Kọmandaati Sọji Ganzallo, sọ ninu atẹjade kan ti Alukoro wọn, Mọruf Yusuf, fi ṣọwọ s’ALAROYE lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu yii, pe ni nnkan bii aago meji aajin oru ọjọ naa lawọn gba ipe pjawiri lori aago pe kawọn tete maa bọ o, ole ti fọ ṣọọṣi, wọn ni wọn ri oju ajeji nile Oluwa loru.
O ni loju-ẹsẹ lawọn ẹṣọ So-Safe ti tamọra, Ọgbẹni Wasiu Ọjẹrinde lo ṣaaju ikọ wọn, ni wọn ba lọ sibẹ, Ọlọrun si ba wọn ṣe e, ṣinkun ni wọn mu jagunlabi yii nibi to gbe n pa radiradi, to n wọna lati sa lọ.
Lẹyin tọwọ ba a laṣiiri tu pe ile meji ọtọọtọ lo ti ṣe wọn ni ṣuta ko too de ṣọọṣi naa loru ọjọ ọhun, o jọ pe foonu jiji ni afojusun afurasi ọdaran yii, tori foonu Itel mẹrin to ji ni wọn ba lọwọ ẹ.
Ọmọkunrin yii ni ilu Ajegunlẹ, ni Ipobẹ, nijọba ibilẹ Ipokia, loun n gbe, ṣugbọn adugbo Agọ Ararọmi, niluu Ilaro, nijọba ibilẹ Yewa, lo ti n waa han awọn eeyan leemọ, bo ba jale tan lo n pada s’Ajegunlẹ to ti wa.
Wọn tun bi i leere ohun to n fi awọn ẹru ole to n ji ṣe, o loun n lu u ta ni gbanjo ni, oun si n fowo ẹ jẹun.
Ṣa, wọn ti fa afurasi ọdaran naa atawọn ẹru ole ti wọn ba lọwọ ẹ le awọn ọlọpaa ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to wa niluu Ilaro lọwọ fun iwadii to lọọrin lori iṣẹlẹ yii. Wọn lawọn ọlọpaa yoo foju ẹ bale-ẹjọ ti wọn ba ti pari iwadii wọn.