Ọmọọleegbimọ aṣoju-ṣofin ipinlẹ Ọyọ fi ẹgbẹ APC silẹ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Aṣofin to n ṣoju ẹkun idibo Isẹyin, Itẹsiwaju, Kajọla ati Iwajọwa, nipinlẹ Ọyọ, nileegbimọ aṣofin apapọ ilẹ yii keji niluu Abuja, Ọnarebu Shina Abiọla Peller, ti kuro ninu ẹgbẹ oṣelu All Progresives Congress (APC).
Ninu lẹta to kọ si alaga wọọdu rẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC, iyẹn Wọọdu kẹsan-an, to wa lagbegbe Koso, nijọba ibilẹ Isẹyin, niluu Isẹyin, lọkunrin ọmọ bibi ilu Isẹyin naa ti sọ ipinnu rẹ yii di mimọ. O ni oun ti fikun lukun pẹlu awọn to yẹ ki oun ba sọrọ ko too di pe oun gbe igbesẹ naa ni ibamu pẹlu ifẹ ọkan awọn eeyan oun lẹkun idibo naa.
Lọdun 2019 ni wọn dibo yan Shina Peller gẹgẹ bii aṣofin to n ṣoju agbegbe naa labẹ ẹgbẹ oṣelu APC.
Eyi ti ọpọ oloṣelu fi maa n du saa fun ti ilu ba dibo yan wọn si, ipo mi-in lọmọ Baba Ọlọwọ Idan du, o fẹẹ dupo sẹnitọ lati maa ṣoju ẹkun idibo Ariwa ipinlẹ Ọyọ nileegbimọ aṣofin apapọ kinni niluu Abuja.
Ṣugbọn ko ri tikẹẹti lati du ipo ọhun gba, Sẹnitọ Fatai Buhari, ẹni to n ṣoju ẹkun idibo naa lọwọlọwọ, lo jawe olubori ninu idibo abẹle ẹgbẹ naa lati ṣoju ẹgbẹ oloṣuṣu ọwọ ninu idibo gbogbogboo ọdun 2023.

ALAROYE gbọ pe nitori ijakulẹ rẹ ninu idibo abẹle ọhun lọkunrin naa ṣe fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ nitori ṣaaju lo ti sọ pe ojooro wa ninu idibo naa, ati pe bi ẹgbẹ onigbaalẹ ko ba fa oun kalẹ, oun yoo lọ sinu ẹgbẹ mi-in lati dupo sẹnitọ oun.

Nigba to n ṣalaye idi to ṣe fi ẹgbẹ naa silẹ nibi lẹta ọhun, Ọnarebu Peller sọ pe iwa ti awọn kan n hu ninu ẹgbẹ naa lodi si eto ijọba awa-ara-wa nitori nṣe ni wọn fipa gbe oludije kan le awọn yooku lori, ati pe bi nnkan ba n lọ bayii, ko si ireti kankan fawọn ọdọ orileede yii, bẹẹ niru iṣesi bẹẹ ko ni i seso rere fun ọjọ iwaju orileede yii.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “nitori ilọsiwaju agbegbe Oke-Ogun ati idagbasoke orileede yii ni mo ṣe n ṣoṣelu. Mo ti ṣepade pẹlu awọn eeyan mi, oun ti wọn fẹnu ko le lori ni pe ka kuro ninu ẹgbẹ APC, mi o si le kọrọ si awọn eeyan mi lẹnu nitori igbayegbadun wọn lo jẹ mi logun”.

Leave a Reply