Ọmọwumi ti dero agọ ọlọpaa o, ija ẹnikan lo n gbe to fi gun Ahmed nigo pa l’Ọta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ẹka ti wọn ti n fọrọ wa awọn apaayan lẹnu wo ni Ọmọwumi Ọyapitan, ẹni ọdun mejilelọgbọn, to n ṣiṣẹ telọ wa bayii, ibẹ ni yoo si wa titi ti wọn yoo fi gbe e lọ si kootu, nitori ọkunrin kan, Muhammed Ahmed, to gun nigo lọrun l’Ọta, tiyẹn si gbabẹ ku ni.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kejila, ọdun 2021 ni Ọmọwumi daran to gbe e de ti ọlọpaa yii.

Ohun to ṣẹlẹ gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣe ṣalaye ni pe ọmọkunrin ti wọn n pe ni Muhammed Ahmed yii fara pamọ si otẹẹli kan ti wọn n pe ni Splendour Guest Inn, l’Ọta, iyẹn lẹyin to ti ji ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta naira (600,000), owo ọga rẹ to ni otẹẹli Hayorlak.

Iṣẹ awọn to maa n ta ọti fawọn eeyan ni Ahmed n ṣe lọdọ ọga rẹ ko too ji i lowo, nigba to ji owo ọhun tan lo lọọ fara pamọ si otẹẹli Splendour. Ọjọ Aje ti i ṣe Mọnde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kejila, ni wọn lo ti fara pamọ si otẹẹli ọhun, to n jaye ori ẹ nibẹ, to si n ṣaye fawọn ọrẹ rẹ kan. Niṣe lo gba yara fawọn iyẹn naa ninu otẹẹli ọhun, ti wọn n ṣe faaji gidi.

Afi bo ṣe di lọjọ Wẹsidee ti wahala de, Ahmed lo fẹsun kan ọkan ninu awọn to gba yara fun lotẹẹli naa pe o ji ninu owo toun fi n ṣaye fun wọn.

Ọrọ naa ni wọn n ba ara wọn fa lọwọ ti Ọmọwumi toun naa wa lotẹẹli Splendour fi da si i. Oun da si i nitori o mọ ẹni ti Ahmed n ba ja ri, ọmọ adugbo kan naa ni wọn.

Bo ṣe da si ija naa ni ko tẹ Ahmed lọrun, nitori iyẹn ri i bii ẹni to n da si ohun ti ko kan an, n lo ba fun Ọmọwumi lẹṣẹẹ lẹnu pe ko panu ẹ mọ, ko ma da si ọrọ awọn.

Nigba naa ni ibinu gbe Ọmọwumi Ọyapitan wọ, loun ba ki igo kan mọlẹ, lo ba pa a poo, ọrun Ahmed lo ki igo naa bọ, biyẹn ṣe mudii lọ silẹ niyẹn, lẹjẹ ba n da lọrun rẹ.

Maneja otẹẹli Splendour, Ọgbẹni Stephen Udo, lo mẹjọ lọ si teṣan ọlọpaa Onipaanu, bi wọn ṣe waa mu Ọmọwumi lọ niyẹn, ti wọn ba Ahmed, ẹni ọgbọn ọdun ninu agbara ẹjẹ, ni wọn ba sare gbe e lọ sọsibitu.

Ko pẹ ti wọn gbe e dọsibitu tawọn dokita fi kede iku rẹ, wọn ni Ahmed ti dagbere faye.

Bayii ni Ọmọwumi to da si ọrọ ọlọrọ ba ara ẹ ni yara ahamọ awọn ọlọpaa, ti CP Lanre Bankọle si ni ki wọn gbe e lọ sẹka to n gbọ ẹjọ ipaniyan, nibi ti wọn yoo ti towe rẹ ti yoo dele-ẹjọ.

Leave a Reply