Oni nigbẹjọ Adedoyin atawọn oṣiṣẹ rẹ yoo bẹrẹ niluu Oṣogbo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Oludasilẹ ileetura Hilton, niluu Ileefẹ, Dokita Rahmon Adedoyin, ati mẹfa lara awọn oṣiṣẹ rẹ ti wọn fẹsun kan pe wọn lọwọ ninu iku akẹkọọ Fasiti Ifẹ lọdun to kọja ni wọn ti gbe de ilu Oṣogbo bayii fun igbẹjọ wọn.

Ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ọṣun to wa niluu Oṣogbo nigbẹjọ naa yoo ti bẹrẹ ni Ọjọruu, Tọsidee, ọsẹ yii.

Akẹkọọ naa, Timothy Adegoke, lo dawati lẹyin to sun si otẹẹli naa, lẹyin iwadii ni wọn ri ibi ti wọn sin oku rẹ si, ti wọn si hu u jade fun ayẹwo, eleyii lo si fa a ti awọn ọlọpaa l’Ọṣun fi mu Adedoyin atawọn oṣiṣẹ rẹ mẹfa.

Lẹyin ti wọn lo ọsẹ diẹ lagọọ ọlọpaa ni ọga agba patapata fawọn ọlọpaa sọ pe ki wọn maa ko wọn bọ niluu Abuja, ti wọn si ko wọn lọ.

Ṣugbọn nigba ti awọn mọlẹbi oloogbe gba agbẹjọro agba, Fẹmi Falana, lati ba wọn ṣẹjọ naa niyẹn beere pe ki wọn taari ẹjọ naa sipinlẹ Ọṣun tiṣẹlẹ ti ṣẹlẹ, bayii ni ọga ọlọpaa patapata jawọ ninu ẹ.

Ẹsun ti wọn fi kan Adedoyin ni pe o ṣe oku Timothy kumọkumọ, nigba ti wọn fi ẹsun meje to ni i ṣe pẹlu igbimọ-pọ huwa buburu, igbiyanju lati paayan, ipaniyan, ati bẹẹ bẹẹ lọ, kan awọn oṣiṣẹ rẹ.

Awọn oṣiṣẹ ti wọn yoo jẹjọ pẹlu Adedoyin ni Adedeji Adeṣọla, Magdalena Chiefuna, Adeniyi Aderọgba, Oluwale Lawrence, Oyetunde Kazeem ati Adebayọ Kunle.

ALAROYE gbọ pe irọlẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ni awọn olujẹjọ de siluu Oṣogbo. Bakan naa ni Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, SP Ọpalọla Yẹmisi, sọ pe loootọ nigbẹjọ naa yoo bẹrẹ lonii.

Ẹgbọn Timothy Adegoke, Gbade, sọ pe awọn ti ṣetan fun igbẹjọ naa ti yoo bẹrẹ naa.

Leave a Reply