Onibaara lu alagbe ẹgbẹ ẹ pa l’Ekoo, o lo n yọju wo abẹ oun nigba toun n tọ

Faith Adebọla, Eko

 Iyalẹnu gbaa niṣẹlẹ aburu kan to waye lagbegbe Victoria Island, l’Ekoo, yii jẹ fawọn eeyan ti wọn gbọ pe onibaara kan lu alagbe ẹgbẹ ẹ pa. Ẹsun to ni oloogbe naa fi kan an ni pe o n yọju wo abẹ ẹ nigba to n tọ.

Miriam ni wọn pe orukọ onibaara ti wọn lu pa ọhun, nigba ti afurasi ọdaran to lu u pa n jẹ Abubakar. Akanda ẹda lawọn mejeeji, ori kẹkẹ arọ ni Abubakar maa n wa ni tiẹ, ibẹ lo ti n tọrọ baara jẹun, nigba ti oloogbe naa kan maa n jokoo sẹgbẹẹ titi, nibi tawọn eeyan ti n fowo ta a lọrẹ.

Ohun ta a ri gbọ ni pe lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ ọdun ileya gan-an niṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ. Onibaara mi-in ti wọn jọ maa n jokoo wa nibi tọrọ ọhun ti ṣẹlẹ, oun lo ṣalaye iṣẹlẹ ọhun. O lo ṣoju oun nigba ti oloogbe ọhun fidi wọ lọọ tọ lọsan-an ọjọ naa lẹbaa igbo eti titi to wa nitosi.

Ṣugbọn bo ṣe pada de lo fẹsun kan Abubakar pe oun ri i pe o n wo abẹ oun nigba toun n tọ, o ni oju oun pẹlu rẹ  ṣe mẹrin bi oun ṣe tọ tan.

Ẹsun yii ni wọn lo bi Abubakar ninu to fi bẹrẹ si i sọrọ fata fata lede Hausa si oloogbe onibaara ọhun, bo ṣe n bu u ni tọhun naa n fesi, to si n sọ pe ootọ loun sọ, oun ko purọ mọ ọn.

Wọn ni bọrọ ṣe dija ree, ti ọkunrin naa si fibinu fa pako kan tọwọ ẹ tẹ nitosi yọ, afi gbaa latari Mariam, ori ẹ lo la a mọ, niyẹn ba ṣubu yakata sori kankere oju ọna ti wọn ti n tọrọ baara nibẹ.

Ere ni, awada ni, nigba tawọn eeyan to kiyesi ohun to ṣẹlẹ fi maa de ibẹ, ọmọbinrin naa ti sọda, apa ati ẹsẹ ti rọ jọwọrọ, ni wọn bi fi tipa wọ Mọla ọhun dide lori kẹkẹ arọ to wa, wọn ni ko yaa gbe ẹran to pa niṣo lagọọ ọlọpaa.

Ninu fọran fidio kan tawọn to wa nibi iṣẹlẹ naa fi sori ikanni ayelujara, ọkunrin naa n sọ pe ko ti i ku, pe boya o kan daku ni, ṣugbọn awọn bọis to wa nibi iṣẹlẹ naa ti bu u laṣọ so, wọn si wọ ọ lọ si teṣan ọlọpaa Victoria Island, ko lọọ maa ji oku to fibinu lu pa ọhun nibẹ.

Leave a Reply