Adewale Adeoye
Lọna ati wa ojutuu si wahala ati rogbodiyan to n ṣẹlẹ laarin ilu lẹyin tawọn adajọ ile-ẹjọ meji kan niluu Kano, dajọ lori oye Emir ilu naa, eyi to ti n da wahala nla silẹ laarin ilu ọhun bayii, Adajọ agba lorileede yii, Olukayọde Ariwoola, ti ranṣẹ pe awọn adajọ ile-ẹjọ meji kan ti awọn oloṣelu ipinlẹ naa n lo lati da wahala nla silẹ laarin ilu naa sipade pataki kan niluu Abuja.
Adajọ ile-ẹjọ meji ti Ariwoola pe sipade pataki naa ni adajọ ile-ẹjọ giga ijọba apapo kan to wa niluu Kano, ati adajọ agba ipinlẹ Kano. Awọn adajọ mejeeji naa ni awọn araalu gbagbọ pe awọn ni awọn oloṣelu ipinlẹ naa n lo bayii lati da wahala nla silẹ laarin ilu naa lori ọrọ oye Emir ilu Kano.
Adajọ SA Amobeda, tile-ẹjọ giga ijọba apapọ to wa niluu Kano, lo dajọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Karun-un, pe ki wọn le Emir Sanusi Lamido Sanusi kuro laafin rẹ to wa ni Gidan Rumfa, loju-ẹsẹ, nitori ti gomina ipinlẹ naa Abba Kabir, ko tẹle ilana to ba ofin mu lati fi Sanusi joye Emir ilu naa. Ṣugbọn ti Adajọ Amina Adamu Aliyu, tile-ẹjọ giga kan nipinlẹ Kano, tun paṣẹ lati da awọn agbofinro gbogbo lorileede yii lowọ kọ, to si ni ojulowo Emir ni Sanusi.
Lọjọ kẹtalelogun, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni adajo ile-ẹjọ giga tijọba apapọ kan niluu Kano tun fofin de ijọba ipinlẹ Kano pe, ko gbọdọ fipa le Emir Aminu Ado Bayero nipo rẹ. Ija ta ni Emir ilu Kano to n lọ laarin Emir Sanusi ati Alhaji Aminu Ado Bayero ti Ganduje fi jẹ tẹlẹ n gbona si i lojoojumọ ni. Inu ile ijọba ipinlẹ naa ni Gomina ipinlẹ ọhun, Abba Kabir, ti fi Emir Sanusi je lọsẹ to kọja, lẹyin ti awọn ọmọ ileegbimọ aṣofin ipinlẹ naa kọkọ wọgi le ofin ti Ganduje fi rọ Sanusi loye lọdun 2020.
Bi Emir Aminu ṣe pada si aafin rẹ lẹyin ode to lọ ni gomina ti ni kawọn agbofinro lọọ fọwọ ofin mu un, igbesẹ naa si da rogbodiyan silẹ laarin ilu, nitori pe ọpọ awọn ọdọ lo ṣe iwode ifẹhonu han kaakiri.
Iwọde tawon ọdọ naa ṣe yii lo mu kijọba ipinlẹ naa tete da awọn agbofinro lọpọ yanturu sita, ki wọn baa le kapa wahala awọn ọdọ naa.
Pẹlu wahala ti ọrọ naa ti da silẹ ati bi idajọ oriṣiiriṣii ṣe n waye lo mu ki Adajọ agba lorileede yii, Onidaajọ Ariwoola, pe ipade pajawiri laarin awọn adajọ mejeejii tawọn oloṣelu ipinlẹ naa n lo lati da wahala silẹ, to si kilọ fun wọn pe ki wọn ma fi ara wọn kalẹ lati maa lo fun ohun to le ṣakoba fun eto idajọ nilẹ wa.