Onifayawọ meji ku, aṣọbode meji fara pa, lasiko ti wọn koju ara wọn nipinlẹ Ogun

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Lọjọ ti ikọlu ti n waye laarin awọn onifayawọ ati aṣọbode nipinlẹ Ogun, ara ọtọ ni ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹwaa yii, loju ọna Ṣagamu Interchange, nibi ti hilahilo ti ba awọn eeyan ti wọn n kọja tiwọn lọ jẹẹjẹ, ti onifayawọ meji jẹ Ọlọrun nipe, ti awọn oṣiṣẹ kọstọọmu meji paapaa fara pa gidi.

Eko lawọn kọsitọọmu to waa pade awọn onifayawọ nipinlẹ Ogun naa ti wa, Zone A, n’Ikẹja, ni wọn ti wa, ọga wọn si ni ọkunrin kan ti wọn pe orukọ ẹ ni  DCC  Hussein .K. Ejibunu.

Alukoro ẹkun aṣọbode Eko yii, DSC Theophilus Duniya, ṣalaye iṣẹlẹ pe mọto akẹru mejila to ko irẹsi ilẹ okeere lawọn ti mu lọjọ naa, awọn si ti n gbe awọn mọto naa pẹlu irẹsi inu ẹ lọ sile ikẹru-si ijọba gẹgẹ bo ṣe tọ. Duniya sọ pe nibi tawọn ti n lọ lawọn onifayawọ ti lọọ kora wọn jọ wa, ti wọn pọ gidi pẹlu awọn nnkan ija oloro bii ibọn atawọn nnkan ija mi-in. O ni awọn ti aanu awọn onifayawọ naa n ṣe pe gbese lo wọle tọ wọn pẹlu irẹsi tawọn gba yii naa ba wọn da si i, bi wọn ṣe doju ibọn kọ awọn niyẹn tawọn naa si da a pada fun wọn gidi.

Agbẹnusọ awọn aṣọbode yii tẹsiwaju pe nibi ija ọhun ni meji ti padanu ẹmi wọn ninu awọn onifayawọ, awọn si ri ẹyọ kan mu laaye ninu awọn afurasi wọn. Duniya fi kun un pe meji ninu awọn oṣiṣẹ awọn paapaa ṣeṣe gidi nibi ikọlu yii.

Bakan naa lo ni ninu mọto mejila to ko irẹsi to lodi sofin wọlu naa, awọn ri mẹrin gba fun ijọba, nigba tawọn mẹjọ ba awọn onifayawọ lọ. O fi kun un pe afurasi tawọn mu ti wa lakolo ijọba pẹlu, awọn ọfisa to si ṣeṣe lọdọ awọn naa si ti n gba itọju lọsibitu.

Ohun to waa mu iṣẹlẹ ọjọ naa le ju tawọn eyi to ti ṣẹlẹ ri ni pe oju ọna ti ọpọ mọto to n lọ si Eko, awọn to n pada si Abẹokuta atawọn to jẹ abule wọn to wa lẹbaa ọna ni wọn n lọ lo ti ṣẹlẹ. Niṣe ni awọn ọkọ ko le kọja mọ, iro ibọn n ro lakọlakọ, awọn mọto to n lọ s’Ekoo n ṣẹri pada, awọn mi-in lọọ gba ọna ojugbo, bẹẹ lawọn mi-in kọju si ọna to yẹ ki wọn kọyin si, wọn si ṣe bẹẹ sọ oju ọna ọhun di orita ko lo mọ, kalulu duro ṣii fun ọpọ wakati, bẹẹ lawọn ẹlomi-in kẹsẹ sọna ti wọn n rin lẹyin ti ikọlu ọhun ti rọlẹ, wọn ko ri mọto kan gbe wọn.

Pẹlu gbogbo ohun to ṣẹlẹ yii, ọga awọn aṣọbode naa, Hussein Ejibunu, sọ pe ikọlu bii eyi ko ni kawọn ṣọrẹ onifayawọ, o lawọn yoo jọ maa ba ara awọn fa a naa ni bi wọn ko ba jawọ. Ọkunrin naa koro oju si bawọn ọdọ to yẹ ko waṣẹ gidi ṣe, ṣe n koju bọ fayawọ, to bẹẹ ti wọn n padanu ẹmi wọn loju ija ti wọn ko si tori ẹ yee ṣiṣẹ buruku naa. O rọ wọn lati wa iṣẹ to ba ofin mu ṣe.

Ṣugbọn awọn tọrọ yii kan ko yee sọ pe awọn ko ni ọna mi-in. Ohun ti awọn onifayawọ yii n wi ni pe bi irẹsi ṣe n wọlu ko ṣẹyin awọn aṣọbode, wọn ni wọn n gbowo lọwọ awọn ni ounjẹ naa ṣe n wọlu. Nigba tawọn ba  sanwo tan, tawọn fori la iku gbe e de aarin ilu, nigba naa lawọn kọsitọọmu kan yoo ni Eko lawọn ti wa ti wọn yoo maa gba irẹsi naa lọwọ awọn.

Wọn ni ohun to jẹ kawọn naa maa doju ija kọ wọn ree, bi yoo si ṣe maa wa niyẹn, nitori ọmọ to ba ni iya oun ko ni i sun, oun naa ko ni i foju ba oorun.

Leave a Reply