Oniṣina lọkọ mi, iyẹn lo ṣe lu magun lara iya alagbo to n yan lale-Ṣade

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ile-ẹjọ ti tu igbeyawo ọlọdun mọkanlelogun to wa laarin obinrin yádirẹsà kan, Ṣade Ayẹni, ati ọkọ rẹ, Ojo Ayẹni, ka nitori ti ko si ifẹ laarin wọn mọ. Igba kan si wa paapaa tobinrin naa dẹ awọn tọọgi si ọkọ ẹ, awọn ẹruuku si lu jatijati si i lara.

Ojo lo gbe Ṣade lọ si kootu l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja, o ni funra oun loun n dana ounjẹ ti oun atawọn ọmọ n jẹ, nitori pe iyawo oun ko ṣe eyikeyii ninu ojuṣe rẹ ninu ile mọ.

Bakan naa lo fẹsun agbere kan iyawo ẹ, o ni oniṣekuṣe obinrin ni, ati pe afaimọ ni ki i ṣe ale lobinrin naa bi akọbi awọn fun nitori gbogbo igba loun funra rẹ maa n sọ pe ọmọ ọlọmọ loun n tọju.

Ninu ọrọ tiẹ, Ṣade sọ pe gbogbo ohun ti olupẹjọ ro lẹjọ pata, irọ lo fi wọn pa, aimọye igba loun ti se ounjẹ fun un ti ko jẹ, pẹlu awijare pe o ṣee ṣe ki oun ti foogun sinu ounjẹ naa. Nigba to ya lo kuku la a mọlẹ foun pe ki oun maa wulẹ dana ounjẹ foun mọ.

Bo tilẹ jẹ pe olujẹjọ yii ko fẹ kile-ẹjọ fopin si igbeyawo awọn, oun paapaa ṣapejuwe ọkọ ẹ gẹgẹ bii alagbere ọkunrin, o ni “Latigba ti mo ti bimọ ẹlẹẹkẹta ni ko ti nifẹẹ mi mọ, o ti ba obinrin mi-in lọ.

“Ko ba mi laṣepọ mọ. O ti to ọdun meji bayii ta a ti jọ jeun pọ gbẹyin. Ki i saabaa sunle, ọdọ obinrin alagbo kan to n yan lale lo n sun. Lọjọ to ba maa sunle, inu palọ lo n sun. O ti gbe bẹẹdi to wa ninu yara lọ si palọ. Ori ẹní ni mo n sun ni temi ninu yara.

“O ti le mi ni magun. Nitori ẹ ni ko ṣe ba mi sun mọ, ko ma baa jẹ pe oun funra ẹ lo maa pada lu magun yẹn. O ti waa pada lu magun naa lọdọ obinrin alagbo to n gbe kiri yẹn. O ti papa fẹ alagbo yẹn bayii, iyẹn ti bimọ fun un.’’

Ṣaaju lolupẹjọ ti royin bi iyawo ẹ ṣe fiya jẹ ẹ laipẹ yii, o ni “Bi awọn tọọgi yẹn ṣe de iwaju ṣọọbu mi lọjọ yẹn ni wọn sọ kalẹ latori ọkada, ti wọn bẹrẹ si i pariwo pe “oun da? Oun da?”.Iyawo mi n naka si mi latinu mọto kan to jokoo si, pe oun niyẹn. Bi awọn tọọgi yẹn ṣe bẹrẹ si i lu mi niyẹn, wọn si ba nnkan ṣọọbu mi jẹ.”

Ile-ẹjọ ti fopin si igbeyawo ọdun mọkanlelogun naa.

Leave a Reply