Oogun lawọn eleyii fi ba iya arugbo sọrọ ti wọn fi gbowo nla lọwọ rẹ

Faith Adebọla, Eko

Mama agbalagba ẹni ọdun mẹrinlelọgọta kan lo sare wọ banki rẹ lọ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kọkanla, ta a wa yii. Bi mama naa ṣe n gbọn lo n laagun lakọlakọ, bẹẹ lohun rẹ si n gbọ pẹlu. Taara ni wọn lo lọ sọdọ ọkan lara awọn oṣiṣẹ banki to wa lori kanta to n gbowo wọle tabi sanwo jade, ti wọn n pe ni Kaṣia, mama naa na iwe sọwedowo ọwọ rẹ si i, o loun fẹẹ gba ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta Naira jade ninu owo to wa lakaunti oun ni kiakia, aṣe mama yii ti ko sọwọ awọn gbaju-ẹ kan ni.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin, to sọrọ yii di mimọ f’ALAROYE sọ pe ni nnkan bii aago mẹrin ku iṣẹju mẹwaa ọjọ naa niṣẹlẹ yii waye, o ni banki ti fẹẹ tilẹkun, ṣugbọn niṣe ni mama yii n bẹbẹ lọdọ awọn ẹṣọ alaabo pe ki wọn jẹ koun wọle, o ni iṣoro pajawiri kan lo de ba oun toun fi nilo owo naa, ati pe nnkan aburu le ṣẹlẹ soun toun ko ba rowo naa gba, o ni ki wọn ṣaaanu oun, ni wọn ba ṣilẹkun fun un.

Wọn ni Kaṣia to fẹẹ sanwo fun mama ti wọn forukọ bo laṣiiri yii lo fura pe afaimọ ni mama naa ko ti lu gudẹ kan, tori bi mama agbalagba ọhun ṣe n ṣe jonijoni, tara ẹ ko balẹ rara, lo mu kiyẹn pe awọn ọga rẹ ni banki ti wọn ko darukọ ọhun, jade si i.

Wọn beere pe kin ni mama naa fẹẹ fowo rẹpẹtẹ bẹẹ ṣe to mumu laya ẹ to bẹẹ, ko sọ ọ, o ni wọn ti loun o gbọdọ sọ ọ o, ki wọn ma jẹ koun sọrọ o, tori wọn ti ni toun bi fi le lanu ori oun sọ fẹdaa alaaye kan pẹnrẹn, ẹsẹkẹsẹ loun maa ku.

Wọn tun bi i pe awọn wo lo sọ bẹẹ fun un, ibẹ si laṣiiri ti tu, o loun o mọ wọn ri, oun o si ba wọn pade ri, afi bi wọn ṣe pe oun lori aago lọjọ naa, wọn ni koun lọọ maa ko owo inu akaunti oun wa werewere tori ọjọ iku oun ti pe, toun ba si fẹ ko yẹ, afi koun sanwo nla ti awọn n beere, o loun o m’ohun ti wọn fi ba oun sọrọ o, oun o tiẹ mọ nnkan toun n ṣe mọ.

O tun jẹwọ pe wọn ti gba ẹgbẹrun lọna aadọrun-un Naira lọwọ oun, iyẹn owo to wa lọwọ oun lasiko ti wọn fi n ba oun sọrọ, o si fikun un pe awọn ọdaju apamọlẹkun-jaye onijibiti ọhun wa nita banki naa, nibi ti wọn ti n duro de owo toun fẹẹ gba, eyi loun fi sare wọle.

Ṣa, wọn fi mama yii lara balẹ, wọn si tẹ ẹka ileeṣẹ ọlọopaa Ogudu, nipinlẹ Eko, laago, kia si ni wọn ti fi awọn ọtẹlẹmuyẹ ṣọwọ.

Ọwọ ba meji ninu awọn gbaju-ẹ mẹta naa, Osadebe Aigbe, ẹni ọdun marundinlogoji, ati Uche Awaize, ẹni ọdun marundinlaaadọta, nigba ti ẹni kẹta wọn raaye sa lọ.

Hundeyin ni awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii, wọn si ti n tọpasẹ afurasi to sa lọ ọhun, atawọn yooku ti wọn jọ n lu jibiti kiri. O ni wọn o ni i pẹẹ maa kawọ pọnyin rojọ.

Leave a Reply