Oogun oloro: Ajọ NDLEA ṣekilọ fawọn ọdaran lẹyin tọwọ tẹ mọkandinlaaadọfa

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Adari ajọ to n gbogun ti oogun oloro nilẹ yii (NDLEA), ẹka tipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Gaura Shedow, ti kilọ fawọn to n fi iwa ibajẹ naa ṣiṣẹ ṣe lati jawọ nibẹ nitori ko si aaye fun wọn mọ.

Lasiko ayajọ gbigbe ogun ti oogun oloro lilo lagbaaye, eyi to waye lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja, lọga agba naa ṣekilọ yii, bẹẹ lo ni ọwọ awọn ti tẹ awọn kan.

Shedow sọ ọ di mimọ pe laarin ọdun kan si asiko yii, awọn afurasi mọkandinlaaadọfa lọwọ ti tẹ kaakiri ipinlẹ Ekiti, bẹẹ lajọ NDLEA ri oogun oloro to le lẹgbẹrun kan kilogiraamu gba lọwọ wọn.

O ni ọkunrin mọkandinlaaadọrun-un ati obinrin ogun lọwọ tẹ fun iwa to jọ mọ gbigbe ati lilo oogun oloro kaakiri awọn ibuba ti wọn ti n huwa laabi ọhun.

Bakan naa lo ni oko ti wọn n gbin igbo si mẹwaa lawọn dana sun, eyi to din diẹ ni ọgọta eeka, yatọ si awọn ibi ikọkọ tawọn ọdaran n gbin igbo si.

O waa sọ pe ki i ṣe pe awọn kan n ko awọn afurasi kiri, awọn tun ti gba iwa buruku naa lọwọ awọn to le ni ọgọrun-un nipasẹ idanilẹkọọ ati igbaniniyanju.

O ṣekilọ fawọn to n fi oogun oloro jaye lati dẹkun iwa naa, paapaa lasiko ti arun Koronafairọọsi n da gbogbo agbaye laamu yii.

Leave a Reply