Ọọni Ifẹ bẹrẹ ayẹyẹ ọdun marun-un to gori itẹ, Alaafin ṣeleri atilẹyin fun un lori iṣọkan Yoruba

Dada Ajikanje

Niṣe ni oriire n yi lu ara wọn fun Ọọnirisa, Ọba Enitan Ogunwusi, pẹlu bi ọba nla naa ṣe tun dana ayẹyẹ ọdun karun-un to gori itẹ awọn baba nla rẹ, lẹyin to ṣe ayẹyẹ isọmọlorukọ arole rẹ, Aderẹmi lọsẹ to kọja.

Ẹsẹ ko gbero nibi ayẹyẹ naa ti awọn ẹgbẹ Oodua World WideGroup ṣagbatẹru rẹ, eyi wọn ṣide rẹ niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ. Awọn ọba, ijoye atawọn eeyan nla nla lawujọ lo peju sibẹ lati ba Arole Oodua, Ọba Ogunwusi, ṣe ayẹye pe o pe ọdun marun-un lori itẹ awọn baba nla rẹ yii.

Ọsẹ meji ni ayẹyẹ ti wọn bẹrẹ lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, yoo fi waye, iṣide ni eyi ti wọn ṣe niluu Ibadan yii gẹgẹ bi ALAROYE ṣe gbọ.

Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi Kẹta, Sultan Sokoto, Alaaji Sa’ad Abubakar, Ọba Kano, Alaaji Aminu Ado Bayero, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, Olubadan tile Ibadan, Ọba Saliu Adetunji, Iyalode ilẹ Egba, Alaba Lawson atawọn eeyan nla nla mi-in lo peju sibẹ.

Ninu ọrọ rẹ, Alaafin Ọyọ, Ọba Adeyẹmi, ṣadura gidigidi fun ọba alade naa, o ni yoo pẹ lori ipo naa kanrin-kese. Bakan naa ni Ọba Adeyẹmi ṣeleri atilẹyin rẹ fun Ọọni lori mimu iṣọkan pada si aarin awọn ọba alaye nilẹ Yoruba.

Ọba Sokoto ṣapejuwe Ọọni gẹgẹ bii eeyan nla to nifẹẹ iṣọkan ati ilọsiwaju orileede yii lọkan. O gboriyin fun un pẹlu bo ṣe n lo ipo ọba naa fun itẹsiwaju Yoruba.

Awọn eeyan nla nla lo peju pesẹ sibi ayẹyẹ naa, ti gbogbo wọn si n gbadura fun Arole Oodua pe yoo pẹ lori itẹ awọn baba nla rẹ.

 

Leave a Reply