Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ọgunwusi, fun Ajobiewe ni mọto nla

Aderounmu Kazeem

Idunnu nla lo ṣubu layọ fun gbajumọ apẹsa nni, Oloye Sulaimọn Ayilara, ẹni ti gbogbo eeyan tun mọ si Ajobiewe, pẹlu bi Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Ẹnitan Adeyẹye Ogunwusi, ṣe fun un ni mọto ayọkẹlẹ tuntun lọjọ, Aje, Mọnde, laafin ẹ n’Ileefẹ, nipinlẹ Ọṣun.

ALAROYE  gbọ pe lasiko ti Ọba Ogunwusi,  n ṣayẹyẹ ọdun marun-un lori apere awọn baba nla rẹ lo ṣohun idunnu yii fun Ajobiewe.

Nigba ti akọroyin wa pe gbajumọ apẹsa yii, o ni, “Ohun idunnu nla lọrọ naa jẹ loju mi o, mo ti n pẹsa kiri, ti mo n kọrin kiri pẹlu, mi o ti i kewi gba iru ẹbun yii ri. Loootọ ni mo ni mọto daadaa, ṣugbọn eyi ti Ọba Ogunwusi fun mi loni-in, aranbara ni, bẹẹ ni mo dupẹ pupọ lọwọ ori ade.”

Ninu alaye ẹ naa lo ti sọ pe lojiji ni oun gbọ ti Ọọni sọ pe ki wọn lọọ pe Ajobiewe wa laarin ero rẹpẹtẹ ti wọn wa laafin n’Ileefẹ, nibi ti kaluku ti waa ba Kabiesi yọ fun ti ayẹyẹ to n ṣe.

“Mo tiẹ kọkọ ro pe Kabiesi fẹẹ ni ki wọn waa pẹsa fun awọn ni, afi bi Arole Oduduwa ṣe sọ pe, ‘loni-in, a oo dun Ajobiewe ninu pẹlu mọto ayọkẹlẹ tuntun.’ Bi wọn ṣe fa kọkọrọ ayọkẹlẹ tuntun le mi lọwọ niyẹn o, Toyota Camry, dudu minijọjọ bayii ni o. Mo dupẹ lọwọ Arole Oodua, Ọba Ogunwusi, bẹẹ ni mo dupẹ lọwọ Ọlọrun Ọba.”

Ọkan pataki ninu apẹsa, ti Ọlọrun fun lẹbun nla ni Ajobiewe, ni nnkan bii ọdun meloo kan sẹyin ni okiki ọkunrin yii kan ninu ere ọlọsẹ mẹtala kan, Feyikọgbọn to gbajumọ daadaa lori tẹlifiṣan kan l’Ekoo.

Latigba naa lawọn eeyan ti mọ ọn gẹgẹ bii agba ọjọgbọn ninu ka ki oriki orilẹ Yoruba.

Leave a Reply